Nnkan ma waa de o! Wọn tun pa Mary l’Akinyẹle

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin tọwọ awọn agbofinro ti tun ba Sunday Shodipẹ, afurasi ọdaran to n pa awọn eeyan kiri nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, ajalu mi-in tun ṣẹlẹ lagbegbe ọhun pẹlu bi awọn amookunṣika ẹda kan ṣe fipa ba ọbinrin kan, Mary Daramọla, laṣepọ, ti wọn si tun ran an lọ sọrun papandodo.

Labule ti wọn n pe ni Alábàtà, nitosi Mọniya, nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan, niṣẹlẹ ọhun ti waye lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Toheeb Ako atawọn ẹgbẹ ẹ ni wọn lọọ ṣiṣẹ laabi naa gẹgẹ bi Baalẹ Alabata, Oloye Rasaq Ajimọti fidi ẹ mulẹ.

Wọn ni nibi tawọn ọdaju eeyan ọhun ti n gbiyanju lati gbe oku ọmọbinrin naa ju sinu igbo lẹnikan to n kọja lọ nitosi ibẹ ka wọn mọ, to si fariwo ta.

Ariwo ọkunrin yii lawọn ara abule naa gbọ ti wọn fi tu jade, ti wọn si mu eyi to n jẹ Jimoh ninu awọn olubi eeyan naa nigba ti awọn yooku sa lọ patapata.

Awọn olugbe ijọba ibilẹ Akinyẹle ti waa rawọ ẹbẹ sijọba lati wa nnkan ṣe si ọrọ iṣekupani ati ifipabanilopọ to n waye lemọlemọ lagbegbe naa lẹnu ọjọ mẹta yii.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni afurasi ọdaran naa ti wa latimọle awọn agbofinro, nibi to ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii ti wọn n ṣe lori iṣẹlẹ yii.

 

Leave a Reply