Nnkan ti yiwọ o,  ile-ẹjọ ni ko sẹni to fipa mu Baba Ijẹṣa lati sọ awọn ohun to wi ni teṣan

Faith Adebọla, Eko

Pẹlu bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe n kadii atotonu ati ẹri wọn ta ko gbajugbaja adẹrin-in poṣonu oṣere tiata nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ile-ẹjọ ti da ẹbẹ afurasi ọdaran naa nu, wọn si ti gba iwe to kọkọ buwọ lu lagọọ ọlọpaa Yaba wọle, nibi to ti jẹwọ pe loootọ loun fọwọ pa ọmọde naa lara, wọn ni ẹsibiiti to muna doko ni ijẹwọ naa jẹ.

Ni kootu to n gbọ awọn ẹsun akanṣe (Special Offenses Court), eyi to wa n’Ikẹja, lọrọ ọhun ti waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ti igbẹjọ tun tẹsiwaju lori ẹjọ ti Baba Ijẹṣa n jẹ ọhun.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo, nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ lori ẹbẹ Baba Ijẹṣa pe kile-ejọ ma ṣe gba akọsilẹ ti wọn loun kọ ni teṣan ọlọpaa Yaba naa wọle, tori niṣe ni wọn fipa mu oun buwọ lu u, ati pe ki i ṣe bọrọ ṣe ri ni wọn kọ sinu rẹ. Adajọ ni awawi lasan loun ka ẹbẹ naa si, tori ko si ẹri to fidi mulẹ pe wọn fipa mu olujẹjọ niwaju oun.

Taiwo ni: “Ti pe ori ilẹẹlẹ lasan ni wọn mu olujẹjọ yii jokoo si ni teṣan ọlọpaa ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu ijẹwọ rẹ. Ko si ẹri kan niwaju ile-ẹjọ yii to fihan pe wọn fiya jẹ ẹ lati jẹwọ ni, tori naa a gba iwe ijẹwọ ti wọn lo kọ naa wọle gẹgẹ bii ẹsibiiti ta ko o, awọn ọrọ to wa ninu rẹ maa ran igbẹjọ lọwọ.

“Ko si ẹni to jẹrii gbe awijare ti olujẹjọ naa ṣe, pe niṣe ni Inpẹkitọ Abigeal Onome to gba ọrọ rẹ silẹ ni teṣan fi ẹtan mu oun, pe toun ba jẹwọ, wọn a tete fi oun silẹ, lo jẹ koun purọ mọ ara oun.”

Ki adajọ too sọrọ yii lawọn agbẹjọro Baba Ijẹṣa ti sọ fun ile-ẹjọ pe awọn fẹẹ kọwe lati rọ ile-ẹjọ ki wọn da ẹjọ naa nu patapata, tori ko lẹsẹ nilẹ, ki wọn si kede pe Baba Ijẹṣa ko lẹjọ i jẹ. Agbẹjọro olujẹjọ, Ọgbẹni Kayọde Ọlabiran, to ṣoju awọn yooku lo parọwa yii.

Ṣugbọn adajọ naa ni oun ko le maa duro gbọ iru ẹbẹ bẹẹ lasiko yii tori kootu ti n pa oju-iwe de fun opin ọdun, o ni ki wọn sọ ẹbẹ wọn di igbẹjọ to maa waye lọdun tuntun, 2020, awọn agbẹjọro tọtun-tosi si lawọn fara mọ ọn.

Bakan naa ni ẹlẹrii to gbẹyin, eyi ti Abilekọ Ọlayinka Adeyẹmi lati ẹka to n gbeja araalu (Directorate of Public Prosecution), ṣeleri lati mu wa ta ko afurasi ọdaran naa yọju si kootu, o si jẹrii.

O ṣalaye niwaju ile-ẹjọ naa pe aṣọ Baba Ijẹṣa to faya ki i ṣe pe wọn lu u lalubami bo ṣe sọ, o ni ọmọbinrin ti wọn tori ẹ fẹsun kan an lo fa aṣọ naa ya mọ ọn lọrun. O lọmọbinrin naa jẹwọ fawọn ọlọpaa lasiko iwadii pe oun loun lu Baba Ijẹṣa, toun si ya aṣọ mọ ọn lọrun. Amọ, o ni ko si akọsilẹ kankan pe ọmọbinrin naa ti waa fẹjọ Baba Ijẹṣa sun lọdọ ọlọpaa lọdun mẹta ṣaaju asiko tiṣẹlẹ yii waye, o ni igba akọkọ tawọn maa gbọ nipa ẹsun naa ree.

Bi ẹlẹrii naa ti n pari ijẹrii rẹ ni olupẹjọ sọ pe awọn o ni ẹlẹrii mi-in mọ, awọn o si ni atotonu mi-in lati ṣe. Eyi tumọ si pe olujẹjọ ati awọn lọọya rẹ ni ọrọ ku si lọwọ bayii lati bẹrẹ awijare wọn lori awọn ẹsun ti wọn fi kan onibaara wọn.

Ṣa, Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ọdun 2022.

Leave a Reply