NNPCL ti fowo kun epo bẹntiroolu, eyi niye ti wọn n ta a bayii

Jọkẹ Amọri

Ileeṣẹ elepo rọbi nilẹ wa, The Nigerian National Petroleum Company Limited (NNPCL) ti tun fi kun iye ti awọn araalu yoo maa ra epo bẹntiroolu bayii. Loju-ẹsẹ ti ikede naa waye si ni awọn onileepo gbogbo ti yi mita wọn si iye owo tuntun yii, ti wọn si ti bẹrẹ si i ta a niye owo yii lẹsẹkẹsẹ.

Ni bayii, ẹgbẹrun kan ati ọgbọn kọbọ (1,030)  ni wọn sọ epo naa da bayii ni ilu Abuja, dipo Naira mẹtadinlaaadọrun-un (897) ti wọn n ta a tẹlẹ.

Ko too di pe wọn kede owo tuntun ti wọn yoo maa ta epo bẹntiroolu yii, aadọrun-un Naira din marun-un, iyẹn (885) ni wọn n ta epo naa niluu Eko

 

Ni bayii, ẹgbẹrun kan din Naira meji (998) ni wọn yoo maa ta a fawọn eeyan ipinlẹ Eko, nigba ti awọn ara Abuja yoo maa ra jala epo kan ni ẹgbẹrun kan ati ọgbọn Naira (1,030)

ALAROYE gbọ pe igbesẹ yii waye pẹlu bi NNPCL ṣe fa iwe adehun to wa laarin awọn ati ileeṣẹ epo Dangote ya lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ Kẹjọ, oṣu yii. Wọn ni awọn ko ni i maa gbe epo fun awọn alagbata mọ, funra wọn ni wọn yoo maa dunaa-dura iye owo ti wọn yoo maa ra epo naa pẹlu ileeṣẹ Dangote.

Leave a Reply