Ipinlẹ Ọṣun ni Nura atawọn ọrẹ ti kọkọ ja Gbenga lole, ni wọn ba tun da a lọna ni Mowe

 Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Awọn gende mẹrin yii, Nura Bashir; ẹni ogun ọdun, Awalu Aliyu; ẹni ọdun mejidinlogoji, Shuaibu Abdul Rasheed; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ati Abdullah Usman toun jẹ ẹni ọdun mẹtalelogun ti wa lẹka itọpinpin awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, ilu ti wọn ti bẹrẹ ole jija, kọwọ too tẹ wọn ni Mowe, ipinlẹ Ogun.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹrin yii, lọwọ awọn ọlọpaa ba wọn, lẹyin ti ọkunrin kan, Gbenga Ṣiyanbọla, lọọ fẹjọ sun ni teṣan Mowe, pe nigba toun n bọ lati ipinlẹ Ọṣun, toun n lọ s’Ekoo, mọto oun yọnu soju ọna lagbegbe Mowe. O ni nibi toun ti n tun un ṣe lawọn okunrin mẹrin kan ti yọ soun, ti wọn si gba foonu Samsung toun n lo lọwọ oun.

Lẹyin iwadii to gba wọn to ọsẹ diẹ, awọn ọlọpaa tọpasẹ foonu Ṣiyanbọla ti wọn gba ni Mowe de ipinlẹ Ọṣun. Ọkan ninu awọn mẹrin to ja ọkunrin naa lole ni Mowe ni wọn ri foonu naa lọwọ ẹ l’Ọṣun, bi wọn si ti mu un lo ṣatọna bi ọwọ ṣe ba awọn mẹta yooku naa.

Nibi iwadii awọn ọlọpaa to n tẹsiwaju ni wọn ti ri i pe awọn ole mẹrin yii ti figba kan fọ ṣọọbu Ṣiyanbọla kan naa, nibi to ti n ta foonu nipinlẹ Ọṣun, wọn ti ji awọn foonu kan lọ nibẹ nigba naa ti ẹnikẹni ko si ri wọn mu.

Nigba ti ori yoo ta ko wọn ṣa, Siyanbọla ti wọn ti kọkọ fọ ṣọọbu ẹ ni wọn tun da lọna ni Mowe, ifisun tiyẹn si lọọ ṣe ni teṣan Mowe lo ṣẹṣẹ jẹ ki aṣiri ohun ti wọn ti ṣe tẹlẹ naa han sita, bo tilẹ jẹ pe o ti fẹjọ ole to fọ ṣọọbu ẹ l’Ọṣun naa sun ni teṣan A Division, Moorẹ, n’Ile-Ifẹ, tẹlẹ.

Awọn foonu ti wọn ti ji ni ṣọọbu naa tẹlẹ ṣi wa lọwọ wọn pẹlu, gbogbo ẹ lawọn ọlọpaa gba lọwọ wọn bi Alukoro wọn ṣe wi.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Edward Ajogun, ti ni ki wọn ko awọn mẹrẹẹrin pada si ipinlẹ Ọṣun ti i ṣe orisun ole jija wọn, kawọn ọlọpaa ibẹ fawọn le kootu lọwọ.

Leave a Reply