Nwakali gba bọọlu fun kilọọbu lẹyin ọdun kan

Oluyinka Soyemi

Lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹta ti balogun ikọ agbabọọlu Golden Eaglets ilẹ Naijiria tẹlẹ, Kelechi Nwakali, ti gba bọọlu fun kilọọbu gbẹyin, o ti kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ fun Huesca, ilẹ Spain, bayii.

Eyi waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, nibi ti kilọọbu naa ti jiya ami-ayo kan si meji lọwọ Mirandes.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ọdun to kọja, ni agbabọọlu ẹni ọdun mejilelogun ọhun gba bọọlu fun kilọọbu gbẹyin, iyẹn lasiko to wa ni FC Porto B, ilẹ Portugal.

Lati igba to ti balẹ ni Huesca loṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, lo ti n gbiyanju lati gba bọọlu ṣugbọn ti nnkan ko bọ si i. Ni bayii ti Nwakali ti bẹrẹ bọọlu ni Huesca, ireti wa pe yoo lanfaani lati kopa fun kilọọbu naa daadaa.

Diamond Foobal Academy ni Nwakali ti kẹkọọ nipa bọọlu ko too lanfaani lati lọ si idije bọọlu ọjẹ-wẹwẹ agbaye lọdun 2015, nibi to ti gba awọọdu agbabọọlu to ṣe daadaa ju.

Okiki yii lo jẹ ko dara pọ mọ Arsenal, ilẹ England, bẹẹ lawọn yẹn ta a fun kilọọbu mẹrin ọtọọtọ nilẹ Netherlands ati Portugal ki Huesca too ra a patapata lọdun to kọja.

Idije agbaye ọjẹ-wẹwẹ ọdun 2013 lo ti kọkọ fẹẹ kopa ki anfaani naa too bọ, lati ọdun 2015 lo si ti n ṣe bẹbẹ fun Naijiria lagbo Golden Eagles ati Flying Eagles ko too bọ si Super Eagles.

Leave a Reply