Ọkọ mi ti lahun ju, ori aja lo maa n gbe ounjẹ pamọ si- Baṣirat

Ọlawale Ajao, Ibadan

“Alainikan-an-ṣe ọkunrin ni mo fẹ lọkọ. Ki i tọju emi atawọn ọmọ. To ba tun fowo ra ounjẹ wale, ori aja lo maa n gbe e pamọ si nitori o maa n yọ ounjẹ gbe wale ni.”

Eyi lọrọ tiyawo ile kan, Basirat Adeyọyin, sọ niwaju igbimọ awọn adajọ nigba to n gbiyanju lati kọ ọkọ ẹ silẹ ni kootu ibilẹ Ojaa’ba to wa ni Mapo, n’Ibadan, lọsẹ to kọja.

Basirat, oniṣowo to fi adugbo Ọlọrunṣogo, n’Ibadan, ṣebugbe yii ṣalaye pe “Ọmọ mi ọkunrin lo tu aṣiri ẹ fun mi pe ori oke àjà lo maa n tọju irẹsi to ba ra wa sinu ile si. Nigba to ba ri i pe mi o si nile lo maa n se e, to si maa n da a jẹ.”

Nigba to n ṣapejuwe ọkọ ẹ gẹgẹ bii ọdaju ati alakooba eeyan, olupẹjọ sọ pe “Nigba ti ara akọbi wa ko ya, o ni oun lọ sile babalawo kan, wọn waa ni ki oun ba mi laṣepọ fun ọjọ meje ki ara ọmọ wa le ya. Nibi ta a ti n ṣe e lọwọ lọjọ keji ni mo ti sare le e dide nigba ti ara ṣadeede bẹrẹ si i ni mi. Nigba ta a de ọsibitu ni wọn sọ fun mi pe oyun oṣu mẹta ti mo ni ti bajẹ mọ mi lara. Aṣe ọkọ mi fẹẹ fi mi ṣoogun owo ni.”

Bo tilẹ jẹ pe oun pẹlu olujẹjọ ko jọ gbe papọ mọ, Basirat rọ ile-ẹjọ lati tu igbeyawo wọn ka, ki ọkunrin naa too gbẹmi oun.

Ọkọ Basirat, Adeniyi Adedoyin, fara mọ kile-ẹjọ tu igbeyawo wọn ka. Amọ ṣaa, o  ta ko ẹsun ti iyawo ẹ fi kan an, o ni loootọ ni babalawo sọ pe ki oun ba a laṣepọ fun ọjọ meje, ṣugbọn ki i ṣe pe oun fẹẹ fi i ṣoogun owo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Funra ẹ lo ko kuro ninu ile. Mo ro pe nitori pe ko nigbagbọ ninu mi mọ ni, o ro pe niṣe ni mo fẹẹ fi oun ṣoogun owo.

“Mo fara mọ kile-ẹjọ yii tu igbeyawo wa ka, ṣugbọn mi o fẹ ki wọn yọnda ọmọ fun un nitori ki i ṣe abiamọ gidi.

“Nitori iwa aibikita to maa n hu nipa itọju awọn ọmọ lo jẹ ki awọn ọkunrin kan ba ọmọbinrin wa laṣepọ lọjọ kan. Njẹ ẹ mọ pe iyawo mi ko tun ka kinni yẹn si, o tun n ta ọja rẹ lọ nigba ti wọn sọ ohun to ṣẹlẹ fun un ni. Emi nikan ni mo ṣe akitiyan bi awọn ọlọpaa ṣe ri awọn ẹni yẹn mu ko too di pe wọn bẹ wa lati fọrọ mọ Ọlọrun.

Igbimọ awọn adajọ kootu ọhun, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, Alhaji Suleiman Apanpa pẹlu Alhaji Rafiu Raji ti fopin si ibaṣepọ ọlọdun mọkanla naa.

Oloye Ademọla ti i ṣe adajọ agba waa pa olupẹjọ laṣẹ lati maa san ẹgbẹrun mẹwaa Naira (N10,000) fun olupẹjọ gẹgẹ bii owo itọju awọn ọmọ wọn mejeeji ti ile-ẹjọ yọnda fun iya wọn lati maa tọju.

Leave a Reply