Ọlalere fọlọpaa mu iyawo ẹ n’Ibadan,  o lo fẹẹ jalẹkun ile oun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nnkan bii wakati meje niyawo ile kan, Coker Ayọkunnu, lo latimọle awọn ọlọpaa, ọkọ to gbe e sile, Ọlalere Coker, lo fọlọpaa mu un, o lo fẹẹ jalẹkun ile awọn, nibi to ti n gbiyanju lati fi ogboju wọle lalẹ ọjọ kan bayii to pẹẹ wọle.

Iwa ka maa pẹẹ wọle lalaalẹ yii atawọn ẹṣẹ mi-in ti Ayọkunnu ṣẹ ọkọ ẹ lo mu ọkunrin naa pe e lẹjọ si kootu ibilẹ Ile-Tuntun to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, ti ile-ẹjọ si tu wọn ka lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

Ara ẹsun ti olupẹjọ yii fi kan iyawo ẹ ni pe ko nitẹriba fun oun atawọn ẹbi oun, bẹẹ ni ki i gbọrọ soun lẹnu, bibẹ loun ṣẹṣẹ maa n bẹ ẹ ko too le ṣe nnkan ti oun n fẹ.

Ẹnjinnia to fi adugbo Odo-Ọna Kekere, n’Ibadan, ṣebugbe yii ṣalaye pe “Aburo mi ọkunrin kan waa gbe pẹlu wa nigba kan, njẹ ẹ jẹ mọ pe iyawo mi le ọmọ yẹn lọ. Kekere tun waa niyẹn, lẹyin to le aburo mi lọ tan, ara iya mi ko ya, wọn waa wa sile wa lati waa gbatọju nitori nọọsi niyawo mi. Bi ara iya mi ṣe ya tan lo ti le wọn lọ.

“Mi o si nile lọjọ yẹn, ibi iṣẹ ni mo wa ti iyawo mi ti pe mi lori foonu, to n sọ fun mi pe oun ti le iya mi lọ o, oun ko si fẹẹ ri ẹbi mi kankan nile wa mọ latoni lọ. Latigba yẹn laaye ti gba a lati maa ṣe ohun to ba wu u pẹlu mi.

”Bo ṣe wu u lo maa n ba dukia mi jẹ. nigba mi-in, o le fọ tẹlifiṣan, igba mi-in, o le binu fọ àwo tabi ko ba nnkan mi-in to ba wu u jẹ. Lọjọ Sannde to kọja lo fi aake ba ilẹkun ile jẹ nitori pe mi o ṣilẹkun fun un nigba to pẹ ko too wọle laajin lọjọ naa. O fẹẹ ja ilẹkun yẹn gan-an ni, ko kan ṣee ṣe fun un ni.

“Ni Monde, ọjọ keji, ni mo lọọ fẹjọ ẹ sun lagọọ ọlọpaa to wa l’Orita Challenge, n’Ibadan. Awọn ọlọpaa obinrin meji ni wọn tẹle mi lọ sile.  Wọn pe e nìpè ọmọluabi lọ sagọọ wọn, ṣugbọn ko lọ, niṣe lo n ba wọn fa wahala, afigba ti awọn ọlọpaa fi tulaasi gbe e lẹyin ti wọn pe teṣan wọn lati beere fun mọto ti wọn fi n gbe awọn afurasi ọdaran.

“Atimọle awọn ọlọpaa ni iba sun lọjọ yẹn bi ki i baa ṣe pe aunti mi lọọ gba beeli ẹ nigba to di pe ile fẹẹ ṣu.”

Olujẹjọ sọ pe oun fara mọ kile-ẹjọ tu igbeyawo awọn ka, ṣugbọn oun fẹ ki wọn mọ pe irọ lọkọ oun fi gbogbo ẹjọ to ro pata pa. O ni ko si ija kankan laarin oun ati iya ọkọ oun, oun si kọ loun le iya naa to fi kuro nile awọn lẹyin ti oun ti tọju ẹ, to si ti gbadun.

Oun paapaa fẹsun kan ọkọ ẹ pe “Odidi oṣu mẹta ni mo fi ṣaisan nigba kan, ọdọ awọn obi mi ni mo ti n gbatọju, ọkọ mi ko si ṣeeṣi yọju si mi lẹẹkan ṣoṣo bayii. Nigba ti mo pada sile lẹyin ti mo gbadun tan, ẹru obinrin mi-in ni mo ba ninu ile, ṣugbọn mi o ba ẹnikankan nile. Ẹbẹ lo pada n bẹ mi nigba ti mo pe e lori foonu pe ṣe iyawo keji lọrọ rẹ kan bayii.

Ninu idajọ ẹ, Oloye Henry Agbaje ti i ṣe oludari igbimọ awọn adajọ kootu naa ti tu igbeyawo ọlọdun mẹẹẹdogun ọhun ka. Olujẹjọ lo yọnda ọmọ mẹtẹẹta to da wọn pọ fun, o si paṣẹ fun olupẹjọ lati maa san ẹgbẹrun mẹẹẹdogun naira fun iya wọn loṣooṣu gẹgẹ bii owo ounjẹ awọn ọmọ naa.

Leave a Reply