Ọpẹ o! Ajeji ti wọn ji gbe n’Ibadan ti bọ lọwọ awọn ajinigbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin bii ogun wakati ti wọn ji ara ilẹ Lebanon kan, Ọgbẹni Hassan Mills gbe, ọkunrin naa ti ri ìdáǹdè gba, o si ti dara pọ mọ awọn ẹbi atawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ẹ ba a ṣe n kọroyin yii.

Ọgbẹni Mills, ẹni to ni oko nla kan ti wọn n pe ni Panorama Farm, laduugbo Mẹkun, nitosi Oke-Alaro, n’Ibadan, lawọn giripa agbebọn kan lọọ ka mọ iwaju ọgba oko rẹ ọhun, ti wọn si ji oun ati amugbalẹgbẹẹ ẹ gbe lasiko ti awọn mejeeji n gbiyanju lati wa mọto jade kuro ninu ọgba oko wọn.

Awọn oṣiṣẹ inu ọgba naa la gbọ pe wọn tẹ awọn agbofinro laago ti awọn ọmọ ogun ajọ eleto aabo ijọba ipinlẹ Ọyọ ti wọn n pe ni Operation Burst fi bẹ sinu igbo ti wọn gbe awọn eeyan naa lọ lati gba wọn silẹ, ki wọn si fi panpẹ ọba mu awọn kọlọransi ẹda to huwa ọdaran ọhun.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, lawọn ọlọpaa yọ ọkunrin alawọ funfun yii nigbekun awọn ọdaju eeyan naa.

Leave a Reply