Ọpẹ o, meji lara awọn mẹrin ti Fulani ji ko l’Ekiti ti gba iyọnda

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ti kede pe wọn ti ṣe awari meji lara awọn mẹrin ti Fulani ji ko lọjọ Wẹsidee ni  Ayetoro-Ekiti.

Alukoro wọn nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, lo ṣe ikede naa laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn akọroyin. O salaye pe awọn meji naa ni wọn ri lori afara kan to wa ni opopona kan to kọja si ilu Ikun-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, nipinlẹ Ekiti.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni deede aago mẹjọ ààbọ̀ alẹ ọjọ lṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn agbebọn ti wọn ko din ni ọgbọn, ya wọ ilu naa pẹlu ohun ija oloro lọwọ,  ti wọn si n yinbọn soke ki wọn too fi ori le ileetura kan ti orukọ rẹ n jẹ Diamond to wa niluu naa.

Ninu ileetura naa ni wọn ti fipa ba ọmọdekunrin kekere kan to jẹ oṣiṣẹ ileetura  naa lo pọ, to si wa ni ẹsẹ kan aye ati ọrun,  bakan naa ni wọn tun fi ada ṣa lara awọn òṣìṣẹ́ ibẹ yanayana.

Alukoro ọlọpaa naa ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ ni pereu lati foju awọn aṣebi naa han si gbangba  nipinle naa.

Ogbeni Abutu ni awọn ọlọpaa ipinlẹ naa ti ṣetan lati gbe eto pataki kan kalẹ ti yoo fi oju awọn aṣebi ati awọn agbebọn han nipinlẹ naa.

“A bẹ gbogbo awọn araalu ati awọn ọdẹ to wa ni ipinlẹ Ekiti pe ki wọn yọnda ara wọn lati maa ta wa lolobo lori ọrọ to jọ mọ iṣẹ awa ọlọpaa ti ti yoo le ran wa lọwọ nigba gbogbo.”

 

Leave a Reply