Ọpẹ o, wọn ti pari ija obinrin toju ẹ yatọ ni Kwara atọkọ ẹ

Stephen Ajagbe, Ilorin

Iroyin ayọ to tẹ wa lọwọ laaarọ oni ni pe ija to wa laarin obinrin ti ẹyin oju oun atawọn ọmọ rẹ yatọ, Risikatu Abdulazeez, ati ọkọ rẹ, Abdulwasiu, ti fẹẹ pari bayii.

Nigba ti ALAROYE ba Abdulwasiu sọrọ lori foonu, o fi idunnu han pe ohun gbogbo yoo lọ soko igbagbe laipẹ, awọn yoo si pada si bawọn ṣe n ṣe lọkọ-laya tẹlẹ.

Wasiu ni, “Ile awọn ẹbi iyawo mi la wa bayii. A ti n yanju ọrọ naa. O da mi loju pe yoo niyanju. Ẹ ṣeun pupọ, ile yin ko ni i daru o.”

O ni awọn obi atawọn ẹgbọn oun lo tẹle oun lọ sile ẹbi iyawo oun lati pari ija to wa nilẹ.

Ṣe lati opin ọsẹ to kọja ni oriṣiiriṣii igbesẹ ti n waye lati ri i pe ija pari. Yatọ si awọn alaṣẹ ijọba to n ba wọn da si i, ẹgbẹ idagbasoke ilu Ilọrin, Ilọrin Emirate Youth Development Association, IEYDA, gbe Wasiu lẹyin lati ṣabẹwo si ẹbi Risikatu lati ri i pe wọn fopin si iyapa to ṣẹlẹ laarin wọn.

Lẹyin ti wọn pẹtu si igun mejeeji ninu ni wọn jọ ya foto papọ pẹlu idunnu.

Leave a Reply