Ọwọ ọlọpaa tẹ ọkan ninu awọn to dana sun eeyan meji n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ki wọn maa dana sun eeyan ti waa fẹẹ di aṣa awọn araalu Ibadan bayii pẹlu bi wọn ṣe tun dana sun eeyan meji laduugbo Oke-Ado ati adugbo Mọlete, n’Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ana.

ALAROYE gbọ pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọkan ninu awọn to dana sun awọn eeyan naa. Laarin aago mẹsan-an si mọkanla aarọ lawọn ara adugbo mejeeji ko taya bọ awọn eeyan naa lọrun, ti wọn si dana sun wọn lọkọọkan laaye ọtoọtọ lori ẹṣẹ to ṣọtọọtọ sira wọn.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ẹsun ijinigbe ni wọn fi kan eyi ti wọn dana sun l’Oke-Ado, wọn ni o so bèbí mọ ẹyin lati fi fa awọn ọmọde loju mọra titi to maa fi ri wọn ji gbe.

Olugbe adugbo Oke-Ado kan ṣalaye pe “Ọmọde kan to n tẹle ọkunrin yii lẹyin nitori bèbí to so mọ ara lẹnikan ri to fi pariwo le e lori pe o fẹẹ ji ọmọ naa gbe ni. Ey lo mu kawọn eeyan pe le wọn lori, ti wọn si dana sun ọkunrin to n dibọn bii were yẹn.”

Ṣugbọn lẹyin ti ọkunrin naa ti jona ku eegun lasan la gbọ pe ọlọ́dẹ ori lasan lọkunrin naa, dipo oju gbọmọgbọmọ ti wọn fi wo o.

Saheed lẹnikan to mọ ọn dele pe orukọ ẹ, o ni awọn jo n gbe adugbo Ọmi-Adio, n’Ibadan ni, ati pe iṣẹ awakọ lo n ṣe tẹlẹtẹlẹ ki awọn adigunjale too fibọn gba mọto to n wa lọwọ ẹ. Iporuuru ọkan to ba a nitori iṣẹlẹ yii lo sọ ọ di ọlọdẹ ori to n rin kiri igboro.

Eeyan meji mi-in ni wọn iba tun ṣe bẹẹ dana sun laduugbo Mọletel, n’Ibadan, l’ọjọ Aje yii kan naa bi ko ṣe tawọn Amọtẹkun, ikọ eleto aabo ilẹ Yoruba ti wọn gba ọkan ninu wọn silẹ, bo tilẹ jẹ pe ẹṣẹ ti wọn ṣẹ ko ti i han si ọpọ eeyan ju awọn to da sẹria fun wọn lọ.

Police Clinic, iyẹn ileewosan awọn agbofinro, to wa ninu ọgba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ni wọn sare gbe ọkunrin ti wọn gba silẹ lọwọ iku oro ọhun lọ fun itọju nitori bi awọn eeyan ṣe lu u ṣe leṣe to.

Nigba to n sọrọ lori awọn iṣẹlẹ wọnyi, Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, bu ẹnu atẹ lu iwa ọdaju ti awọn ara Oke-Ado ati Mọlete hu si awọn eeyan ti wọn fura si gẹgẹ bii ọdaran wọnyi.

Kọmiṣanna, ẹni to sọrọ ọhun nipasẹ Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Olugbenga Fadeyi, fi kun un pe ọpọ ẹmi alaiṣẹ lawọn eeyan yoo maa fi ṣofo bi wọn ba n ṣe bayii ṣedajọ latọwọ ara wọn lai fi ọrọ to awọn agbofinro leti.

O ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa awọn iṣẹlẹ iṣekupani lọna aitọ mejeeji naa ati pe ọwọ ti tẹ ọkan ninu awọn to huwa aibofinmu naa.

Leave a Reply