Ọwọ ti tẹ awọn to dana sun agọ ọlọpaa ni Isẹyin

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ mẹsan-an ninu awọn afurasi ọdaran to dana sun agọ ọlọpaa to wa niluu Isẹyin.

Lọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020 yii, ti i ṣe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, lawọn ọmọ iṣọta lo oore-ọfẹ iwọde ti awọn ọdọ n ṣe lati ri i pe ijọba apapọ fopin si SARS, ti wọn si ji dukia awọn agbofinro ko ninu agọ ọlọpaa to wa niluu Isẹyin, ko too di pe wọn dana sun teṣan naa.

Gbogbo ibọn AK 47 ti awọn janduku wọnyi foju kan ninu teṣan naa ni wọn ji lẹyin ti awọn ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ lasiko naa ti sa asala fẹmi-in wọn. Bakan naa ni wọn ji awọn ẹru bii ọkada, kẹkẹ Nàpẹ́ẹ̀pù ati bẹẹ bẹẹ lọ ko ninu teṣan naa.

Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdahan ọhun fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, sọ pe agọ ọlọpaa marun-un lawọn janduku ọhun dana sun lasiko iwọde wọn lọsẹ to kọja, teṣan ọlọpaa ilu Isẹyin naa si jẹ ọkan ninu wọn.

CP Enwonwu sọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja, lawọn agbofinro lọọ ka awọn bàséjẹ̀ eeyan yii mọ ibuba wọn lẹyin ti awọn ọmọluabi eeyan kan lawujọ ti ta awọn ọlọpaa lolobo nipa wọn.

Orukọ awọn afurasi ọhun ni Taoreed Hamsat, tawọn eeyan tun mọ si Shorẹnrlex, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26) ; Moshood Fatai (Elewurẹ), ẹni ọdun mọkandinlogoji (39); Isiaka Ọlaniyi, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32); Tajudeen Ibrahim (Aji), ẹni ogoji (40) ọdun ati Musbau Abubakar, ẹni ọdun mọkanlelogun (21) tawọn ẹgbẹ ẹ tun mọ si Stainless.

Awọn yooku ni Sikiru Aliu, tawọn eeyan ẹ tun mọ si fọtíín-fọtín-ìn (1414), ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25); Fasasi Fatai, ti wọn tun n pe ni Lemọn, ẹni ọdun ẹni ọdun mẹrinlelogun (24); Raheem Toheeb, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ati baba ẹni ọdun mejilelogoji (42) kan to n jẹ Adeleke Akeem.

Lara dukia ijọba ti wọn ji ko lagọọ ọlọpaa ilu Isẹyin, eyi ti awọn agbofinro bá lákàtà wọn lẹyin tọwọ tẹ wọn ni ọkada Bajaaji kan, kẹkẹ NAPEP kan ti nọmba ẹ jẹ DGB 215 QK, ẹrọ amunawa kekere kan ati aago ara ogiri kan.

CP Enwonwu sọ pe laipẹ lawọn afurasi ọdaran wọnyi yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti awọn agbofinro ba pari iwadii wọn.

Leave a Reply