Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori bi wọn ṣe dana sun ṣọọbu bii mẹẹẹdogun kan ninu ọja Agbeni, n’Ibadan, lẹyin ti wọn ti kọkọ ji gbogbo awọn ọja to wa nibẹ ko, Ọga agba awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti gbe igbimọ awọn atọpinpin dide lati ṣewadii iṣẹlẹ naa, meji ninu awọn afurasi ọdaran ọhun lọwọ awọn agbofinro si ti ba.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi lo fidi iroyin yii mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin ALAROYE n’Ibadan.
Ni nnkan bii aago mẹfa aaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lawọn ọbayejẹ ẹda kan ja ilẹkun awọn ṣọọbu ti ko din ni mẹẹẹdogun niye, ti wọn si dana sun gbogbo wọn lẹyin ti wọn ji awọn ọja inu wọn ko tan.
ALAROYE gbọ pe awọn araadugbo naa ni wọn sare tẹ awọn panapana laago lati tete pana ọhun ko too burẹkẹ tan, ṣugbọn awọn janduku ọhun ko jẹ ki wọn le ṣiṣẹ naa, òkò ati apola igi ni wọn fi le wọn lọ. Eyi ni ko jẹ ki wọn le tete pana naa titi to fi burẹkẹ gidi.
Ina to n jo yii kọ lo ko awọn olugbe Agbeni sinu ibẹru bojo bi ko ṣe ti iro ibọn to n ro lakọlakọ nigba ti awọn ọmọ ogun ikọ eleto aabo ijọba ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst fija pẹẹta pẹlu awọn janduku naa, ti wọn si jọ n yinbọ ranṣẹ sira wọn latọọkan.
Gegẹ bo ṣe fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa, SP Fadeyi sọ pe “Lọgan ta a ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii ni kọmiṣanna ọlọpaa ti gbe igbimọ atọpinpin dide lati ṣewadii nipa iṣẹlẹ yẹn.
“Meji ninu awọn afurasi ọdaran naa lọwọ ti tẹ bayii, iwadii ṣi n tẹsiwaju lati ri awọn yooku mu, ki gbogbo wọn le jiya to ba tọ si wọn labẹ ofin”.