Oṣeni lu awọn eeyan ni jibiti l’Akurẹ, lo ba sa wa s’Ekoo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Oṣeni Musliu Maja, latari ẹsun jibiti lilu ti wọn fi kan an.
Oṣeni ni wọn lo fi ara rẹ han gẹgẹ bii oludasilẹ ileepo Forte to wa loju ọna Ondo, niluu Akurẹ, lati lu ẹnikan ta a forukọ bo lasiiri ni jibiti owo to to bii miliọnu kan ataabọ Naira.
Ohun ta a gbọ ni pe afurasi ọhun ti figba kan jẹ adari ileepo naa loootọ  ki wọn too yọ ọ bii ẹni yọ jiga lọdun 2005.
Ọdun kan lẹyin ti wọn yọ ọ tan, ìyẹn lọjọ kẹwaa, osu kẹta, ọdun 2006, lo ṣẹṣẹ lọọ fi haya fun ẹlomi-in,  to si gba miliọnu kan ataabọ.
Wọn ní Oṣeni gbiyanju lati da ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta Naira (#600, 000) pada ninu owo naa nigba tọrọ ọhun kọkọ fẹẹ di ariwo, ṣugbọn lẹyin-o-rẹyìn lo sa kuro l’Akurẹ, to lọọ sapamọ síbi kan niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, nibi tọwọ tí pada tẹ ẹ nibẹrẹ ọsẹ ta a wa yii.

Alakooso agba fajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo, Dokita Hammed Abọdẹrin, ni o ṣee ṣe kí afurasi ọhun foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun bii mẹta ọtọọtọ ti wọn fi kan an.

Leave a Reply