Oṣiṣẹ CAF to waa mojuto idije Naijiria ati Ghana l’Abuja ti ku o

Faith Adebọla
Bi gbogbo eeyan ba gbagbe wahala to waye lasiko ere bọọlu laarin Naijiria ati orileede Ghana ti wọn fẹẹ fi mọ ẹni ti yoo ṣoju ilẹ Afrika ninu wọn lasiko idije ife-ẹyẹ agbaye, awọn mọlẹbi dokita kan to waa ṣiṣẹ nibi ifẹsẹwọnsẹ naa, Dokita Joseph Kabungo, to jẹ ọmọ orileede Zambia to ku lojiji ni papa iṣere MKO Abiọla ko ni i gbagbe laelae.
Ọkunrin yii jẹ ọkan ninu awọn dokita ti ajọ CAF maa n lo lati ṣayẹwo si awọn agbabọọlu boya wọn mu awọn oogun to maa n jẹ ki ara ṣiṣẹ ju bo ṣe yẹ lọ tabi awọn oogun mi-in ti ajọ naa fofin de.
Iṣẹ yii naa la gbọ pe o waa ṣe niluu Abuja lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ti Naijiria ati Ghana koju ara wọn lasiko isọri keji ifẹsẹwọnsẹ wọn, nibi ti wọn ti jọ gba ayo kọọkan sile ara wọn.
Ṣugbọn ibinu lawọn alatilẹyin Super Eagles da bolẹ pẹlu bi wọn ko ṣe rọwọ mu ninu idije naa. Awọn kan ni lasiko ti wọn ya wọ papa iṣere naa ni wọn ṣakọlu si ọkunrin ilẹ Zambia naa. Awọn mi-in ni ẹru lo ba a ti ọkan rẹ si daṣẹ silẹ lojiji to fi ku.
Ohun to daju ni pe Dokita Kabungo ti jade laye ki wọn too gbe e de ileewosan, ko si ti i sẹni to le fidi bi iku rẹ ṣe wa mulẹ.
Niṣe lọrọ di bo-o-lọ-o-yago, ẹni-ori-yọ-o-di’le, ni papa iṣere nla ti Moshood Abiọla, to wa niluu Abuja, laṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, nigba tawọn ero iworan dapọ mọ awọn janduku, ti wọn si ya bo papa iṣere naa, ti wọn din dundu iya fawọn alakooso ajọ to n ri si ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ wa, Nigeria Football Federation (NFF), wọn le awọn agbabọọlu Super Eagles, ẹsẹ wọn ko balẹ, bẹẹ ni wọn ba awọn dukia olowo iyebiye jẹ ni papa iṣere nla naa.
Akọlu yii ko ṣẹyin ibinu to ru bo awọn alatilẹyin (supporters) fun ikọ agbabọọlu Super Eagles ati awọn ero iworan mi-in loju, pẹlu awọn janduku to wa nitosi papa iṣere naa latari bi Super Eagles ṣe fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ Black Stars lati orileede Ghana, to waye nirọlẹ ọjọ naa.
Ifẹṣẹwọnsẹ ọhun ni yoo pinnu ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo ṣoju ilẹ Afrika lasiko idije fun ife-ẹyẹ agbaye to maa waye lorileede Qatar, lọdun 2022 yii. Ọpọ eeyan lo fẹẹ wo ibi ti ere naa yoo ja si, niṣe ni papa iṣere naa kun akunfaya, ori iduro lawọn ti ko raaye jokoo wa.
Super Eagles ni lati bori ifẹsẹwọnsẹ ọhun lati pegede fun idije ifẹ-ẹyẹ agbaye naa, tori ọmi ni wọn ta pẹlu Black Stars ni ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ to waye lorileede Ghana, lọjọ mẹrin ṣaaju.
Bo tilẹ jẹ pe ọmi ni ifẹsẹwọnsẹ ti alẹ Tusidee yii ja si, tori ami-ayo kọọkan ni wọn gba wọle ara wọn, Black Star lo peregede, latari ami-ayo kan ti wọn gba wọle akẹgbẹ wọn nigba ti wọn ka wọn mọle.
Saa akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa ni wọn ti gba ami-ayo kọọkan ọhun, Black Stars lo si kọkọ gba bọọlu wọle ni iṣẹju mọkanla ti wọn bẹrẹ, ki Super Eagles too da tiwọn pada lẹyin iṣẹju meje, ọpẹlọpẹ kamẹra ti wọn fi n ka ere naa silẹ, kamẹra yii ni rẹfiri lọọ wo lati mọ ohun to waye loju ile awọn Black Stars, lo ba fọn fere pe bọọlu agbesilẹ-dojukọ-goli, eyi ti wọn n pe ni pẹnariti ni ki Super Eagles gba, wọn si gba a wọle.
Titi ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi pari, ko sẹni to tun rẹyin awọn ẹnikeji, bẹẹ ni Black Star fi yege fun Qatar 2022.
Ifidirẹmi yii bi awọn ero naa ninu, niṣe ni wọn ya bo papa iṣere naa, ko si ṣee ṣe fawọn agbofinro lati koju wọn, tori ero naa pọ gidi, taara ni wọn lọ sibi tawọn alakooso NFF jokoo si, wọn lu awọn meji tọwọ wọn ba lalubami, bo tilẹ jẹ pe awọn yooku tete fere ge e.
Bakan naa lawọn janduku naa ba aga ijokoo ọlọla, ati aga ijokoo awọn kooṣi to wa leti papa iṣẹre naa jẹ, wọn fọ gilaasi ti wọn fi ṣẹṣọ sibẹ, wọn si fa awọn ike ati paali to wa lagbegbe naa ya.
Ṣugbọn ko pẹ tawọn ṣọja atawọn agbofinro mi-in fi de ibi iṣẹlẹ ọhun, wọn le awọn janduku naa jade, wọn lu ẹnikẹni tọwọ wọn ba, wọn si wa nibẹ titi tohun gbogbo fi rọlẹ.

Leave a Reply