Oṣiṣẹ ileewosan alabọọde ko Korona ni Meiran, nijọba ba ti ibẹ pa

Adefunkẹ Adebiyi

Titi gbọin ni ileewosan alabọọde to jẹ ti ijọba ni Meiran (Meiran Primary Health Care Centre), wa bayii. Ijọba ipinlẹ Eko lo ti i nitori ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ibẹ to ko arun Korona.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni igbesẹ yii waye, nigba ti Alaga agbegbe Idagbasoke Agbado/Oke-Odo, Ọgbẹni David Famuyiwa, paṣẹ pe ki wọn ti ọsibitu naa latari oṣiṣẹ to ti ni Korona nibẹ, ko ma baa di pe kinni naa yoo tun maa ran mọ awọn eeyan mi-in ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ ati awọn ti wọn ba wa fun itọju.

Bakan naa ni alaga yii pe fun wiwa awọn mi-in ti wọn ti ni nnkan an ṣe pẹlu ẹni to ni Korona yii, awọn oṣiṣẹ yooku atawọn alaarẹ to n gbatọju, bẹẹ ni wọn ti ya ẹni to ni aisan naa sọtọ gẹgẹ bii aṣẹ NCDC.

Amọran ti waa lọ sọdọ awọn olugbe Meiran ati agbegbe ẹ, pe ki wọn ṣọra fun arun yii, ki wọn tẹle ofin gbogbo to de Korona lati dẹkun itankalẹ rẹ lawujọ.

Leave a Reply