Oṣiṣẹ mọṣuari ge ori oku olokuu, o ta a fawọn afeeyan ṣetutu l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abeokuta
Bawọn ọdaran ko ṣe jẹ ki alaaye rimu mi lasiko yii, bẹẹ ni wọn o jẹ ki oku naa sinmi, pẹlu bọwọ awọn ẹṣọ alaabo ṣe tẹ afurasi ọdaran kan, Lukman Kushimọ. Oṣiṣẹ ileegbokuu-si ni, ṣugbọn niṣe lo lọọ bẹ oku olokuu kan lori feu, o si ta a fawọn to fẹẹ feeyan ṣoogun owo lẹgbẹrun lọna aadọta Naira l’Abẹokuta.
Awọn ẹṣọ alaabo So Safe, ti wọn n ṣiṣẹ l’Abẹokuta ni wọn mu ọkunrin yii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii.
Alukoro So Safe, Ọgbẹni Mọruf Yusuf, sọ pe Ojule kẹsan-an, adugbo Abule Ọlọni, lagbegbe Oke-Yidi, niluu Abẹokuta, lafurasi ọdaran yii n gbe, o si n ṣiṣẹ nile igbokuu-si aladaani MABOD, eyi to wa lagbegbe Oke-Yidi kan naa, oun lo n ba wọn ṣe oku lọ́jọ̀ ni mọṣuari ọhun.
Gẹgẹ bi alaye ti wọn lo fẹnu ara ẹ ṣa nigba tọwọ tẹ ẹ, o jẹwọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, lawọn mọlẹbi ọmọkunrin to ku sọsibitu FMC (Federal Medical Centre) to wa n’Idi-Aba, l’Abẹokuta, gbe oku naa wa sile-igbokuu-si toun ti n ṣiṣẹ, wọn ni koun ba wọn si in. Aisan kindinrin to daṣẹ silẹ ni wọn lo pa ọdọmọkunrin naa lẹyin itọju.
Lẹyin ti wọn sanwo, niṣeju awọn mọlẹbi naa ni Lukman ti bẹrẹ si i gbẹ ilẹ, o si sin oku naa si itẹkuu wọn ni nnkan bii aago meje alẹ, lawọn olokuu ba lọ ni tiwọn.
Ṣugbọn gẹrẹ ti wọn pẹyinda, ni idaji ọjọ keji, Tusidee, Lukman tun yọ ṣọbiri ti oku yii, o hu u pada, o si fada gba ori kuro lọrun oloogbe naa. Bo ṣe ge ori naa tan to n da yeepẹ bo ageku oku naa ninu koto lawọn ẹṣọ So Safe ka a mọ, lo ba fija pẹẹta pẹlu wọn, ṣugbọn wọn kapa ẹ.
Wọn lafurasi naa tun jẹwọ pe Oloye Ifaloniṣe, tawọn eeyan mọ si Lanroye, lo bẹ oun lori naa, ori tutu lo ni koun ba oun wa, ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000) lawọn jọ ṣadehun fun ori kan, wọn si ti ni ibi ti wọn ti maa pade lọjọ naa, ibẹ lo fẹẹ gbe ori oku naa lọ.
Ṣa, wọn ti n dọdẹ Lanroye naa, ko le sọ tẹnu ẹ, ṣugbọn wọn ko ti i ri i mu, wọn si ti fi Lukman ṣọwọ si ẹka ọtẹlẹmuyẹ lolu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun. Eleweeran lo wa bayii pẹlu ẹsibiiti rẹ, wọn ti n ba iṣẹ iwadii lọ.

Leave a Reply