Oṣiṣẹ wa to ba gbowo ẹyin atẹni to fun un yoo foju bale-ẹjọ-FRSC

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ajọ ẹṣọ alaabo oju popo (FRSC), ti kede pe eyikeyii ninu awọn oṣiṣẹ awọn to ba gba owo ẹyin pẹlu ẹni to fun un lowo ọhun yoo foju bale-ẹjọ bi aṣiri iwa bẹẹ ba le tu pẹnrẹn.

Igbakeji ọga agba ajọ naa to tun jẹ adari ẹkun Eko ati Ogun, Kọmanda Imoh Etuk, lo sọrọ yii nigba to ṣabẹwo si olu ileeṣẹ naa l’Abẹokuta.

Ọkunrin naa ṣalaye pe iṣẹ kan gboogi ti ajọ yii wa fun ni pipese aabo ẹmi ati awọn ohun irinsẹ loju popo, nipa bayii, ko si idi kan fun ẹnikẹni ninu awọn oṣiṣẹ awọn lati gba owo abẹtẹlẹ, bẹẹ ni ko yẹ ki awọn to n wakọ tabi ọkada naa fun wọn lowo kankan.

O ni nitori ẹ lawọn ṣe maa n da wọn lẹkọọ lọpọ igba, ṣugbọn to ba ṣẹlẹ pẹnrẹn pe oṣiṣẹ kan gbowo ẹyin lọwọ awakọ lẹyin gbogbo idanilẹkọọ ati ẹtọ gbogbo tijọba n ṣe fun wọn, atẹni ti wọn fun lowo atẹni to fun un ni wọn yoo jọ foju ba ile-ẹjọ lati jiya ẹṣẹ wọn.

Fun idi eyi, o ni ki ẹnikẹni ninu araalu ma ṣe gbiyanju lati fun awọn oṣiṣe FRSC lowo ẹyin bo ṣe wu ko kere to.

Nigba to n kin ọga agba lẹyin, Kọmanda ileeṣẹ naa nipinlẹ Ogun, Ahmed Umar, sọ pe kọmandi FRSC nipinlẹ Ogun yoo tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ lati ri i pe ijamba oju popo dinku si i.

O lawọn ko ni i woju ẹnikẹni to ba tapa sawọn ofin to de iṣẹ tawọn n ṣe yii, ẹni to ba ṣẹ yoo jiya labẹ ofin ni.

Leave a Reply