Faith Adebọla
Gbọngan nla kan, to kun fọfọ fun itan, awọn nnkan iranti aṣa ati iṣẹmbaye ilẹ Yoruba, taye ọjọun ati tode oni, ti wọn pe ni Ibudo Aṣa Yoruba Agbaye, yoo di lilo fun gbogbo eeyan. Igbakeji aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lo maa ṣi i.
Ayẹyẹ ti wọn maa fi ko ibudo naa jade bii ọmọ tuntun yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni gbọngan nla ti John Paul keji, eyi to wa ninu ọgba Fasiti Ibadan, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade kan ti ẹni to ṣagbatẹru kikọ ibudo aṣa yii, Oloye Alao Adedayọ, alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ ALAROYE fi lede, o ni apa
akọkọ ni ti ṣiṣi ibudo aṣa yii, eyi ti wọn pe ni International Center for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC). Apa keji ni ṣiṣafihan itan to da lori bi Ibudo Aṣa Yoruba Agbaye naa ṣe bẹrẹ, bi wọn ṣe loyun ẹ, titi to fi dodidi, ti wọn si n ko o jade fun ilo tonile-talejo.
Yatọ si igbakeji ilẹ wa, ọpọ awọn ọba alaye atawọn gomina ilẹ Yoruba ni ireti wa pe wọn yoo pẹsẹ sibi ayẹyẹ pataki yii.
Gomina ipinlẹ Ondo, to tun jẹ alaga awọn gomina ilẹ Yoruba ni Iwọ-Oorun/Guusu Naijiria, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ni yoo ko awọn gomina ipinlẹ Ọṣun, Ogun, Eko, Ọyọ, Ekiti ati Kwara sodi wa sibi ayẹyẹ naa.
Alaafin tilẹ Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta, ni alaga ọjọ naa.
Bakan naa ni ireti wa pe Ọọni tilẹ Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji, Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, ati ọpọ awọn ọba alaye ilẹ Yoruba mi-in yoo wa nikalẹ lọjọ naa.
Bi Alao Adedayọ ṣe wi, igbesẹ to maa fitan tuntun balẹ nilẹ Yoruba ni ayẹyẹ ọjọ naa yoo jẹ, ibudo naa yoo si jẹ ọkan to ṣara ọtọ ninu itọju awọn nnkan iṣẹmbaye, aṣa ati iṣe iran Yoruba ati ilẹ adulawọ.
Ti wọn ba pari rẹ, Adedayọ ni Ibudo naa maa ni ile ikoweesi nla kan to maa kun fọfọ fawọn iwe akagbadun oriṣiiriṣii, gbọngan nla ti wọn yoo ṣe awọn nnkan iṣẹmbaye lọjọ si, ibi igbafẹ kan, yara ti awọn fọran ati nnkan iranti tigbalode yoo wa, abule igbọrọsafẹfẹ ati ti fiimu, ọgba ẹranko atọwọda kan, atawọn nnkan pataki mi-in.
Adedayọ ni idi pataki ti iru ibudo yii fi ṣe pataki ni pe “ko ti i si ibudo kan pato kari aye tawọn oluṣewadii ataraalu ti le ri akojọpọ gbogbo awọn nnkan itan, iṣẹmbaye ati aṣa Yoruba loju kan naa, bo tilẹ jẹ pe diẹdiẹ, awọn nnkan wọnyi wa kaakiri awọn ileewe atawọn ọgba itọju iṣẹmbaye kọọkan.”
Adedayọ ni iṣẹ titẹ iweeroyin Alaroye jade toun n ṣe lo tubọ jẹ koun mọ nipa alafo akojọpọ awọn nnkan iṣẹmbaye ati aṣa Yoruba yii, eyi lo si mu koun bẹrẹ igbesẹ kikọ ibudo nla yii.