Oṣogbo ni Ridwan ti maa n ji awọn ọmọ gbe lọọ ta n’Ibadan, awọn Amọtẹkun ti mu un

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ti tẹ ọmọdekunrin kan, Ridwan Kasali, lori ẹsun ijinigbe, wọn si ti fa a le awọn agbofinro lọwọ.

Nibi to ti n rin gberegbere kaakiri lagbegbe Zone 6, ni Capital, niluu Oṣogbo, ni awọn araadugbo ti fura si i, ti wọn si beere ohun to sọnu lọwọ rẹ to n wa kaakiri, nigba ti ko ri ọrọ gidi kankan sọ ni wọn pe awọn Amọtẹkun si i.

Alakoso Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ṣalaye pe ninu iwadii ni Ridwan ti jẹwọ pe awọn ọmọ kekeke marun- un loun ti ji gbe l’Oṣogbo lọ si Ibadan.

Shittu sọ siwaju pe awọn ti fa afurasi naa le ọlọpaa ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi “Awọn araadugbo ti wọn fura si irin rẹ ni wọn mu un, bi wọn si ṣe pe wa la lọ sibẹ. Ninu iwadii lo ti jẹwọ pe ọmọ marun-un loun ti ji gbe l’Oṣogbo, ti oun si ko wọn lọ sibi ti wọn ti pa wọn ni Ibadan.

“O sọ fun wa pe agbegbe kan loun ti wa niluu Ibadan, ilu Oṣogbo loun si ti waa maa n ji awọn ọmọ kekeke gbe.”

Leave a Reply