Oṣu kẹjọ nigbẹjọ baba ọlọdẹ to pa Kehinde l’Oṣogbo ati pasitọ to gbe ori rẹ fun yoo bẹrẹ

Florence Babaṣọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti gbe baba ọlọdẹ kan, Ọgbẹni Adewunmi Gbadamọsi, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o yinbọn fun ọmọdekunrin kan, Kehinde, to si ge ẹya-ara rẹ si wẹwẹ, lọ sile-ẹjọ Majisreeti ilu Oṣogbo lati sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ.

Bakan naa ni Pasitọ Reuben Adetunji, ẹni ti baba ọlọdẹ naa sọ pe oun gbe ori Kehinde fun fara han ni kootu, ti adajọ si sọ pe ki wọn lọọ maa gbatẹjun lọgba ẹwọn titi di oṣu kẹjọ, ọdun yii, tigbẹjọ yoo bẹrẹ ni pẹrẹu lori ọrọ wọn.

Ogunjọ, oṣu karun-un, ọdun yii, la gbọ pe wọn huwa naa ni IfẹOluwa Community, Oke-Baalẹ, niluu Oṣogbo. Baba ọlọdẹ yii pẹlu ifọwọsowọpọ Adewumi Gbadamọsi, Saka Akeem ati Rasheed Ajani ni wọn jọ ṣiṣẹ naa.

Ẹsun marun-un ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ lati huwa buburu, ipaniyan, kiko awọn ẹya ara eeyan kaakiri ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn fi kan awọn olujẹjọ maraarun, eyi to si nijiya labẹ abala okoolelọọọdunrun o le mẹrin, okoolelọọọdunrun o din ẹyọ kan ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta o din mẹta abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ Majisreeti naa, Adijat Ọlọyade, sọ pe ki agbefọba gbe ẹda iwe ẹsun awọn olujẹjọ lọ si ẹka eto idajọ fun imọran lori ẹ.

O ni ki wọn lọọ fi wọn pamọ ṣogba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun yii, tigbẹjọ yoo bẹrẹ lori ọrọ wọn.

 

Leave a Reply