Oṣu kẹsan-an ọdun yii nipinlẹ Ọṣun yoo ko awọn Amọtẹkun rẹ jade 

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alaga igbimọ to n ri si iṣakoso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Isah Aderibigbe, ti sọ pe ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ naa yoo di kikojade faye ri.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lo ṣalaye pe fọọmu ẹgbẹrun meji lawọn gbe sita fawọn ti wọn nifẹẹ lati darapọ mọ Amọtẹkun, eeyan to si le ni ẹgbẹsan (1647) ni wọn gba fọọmu naa.

Aderibigbe sọ siwaju pe awọn jokoo lati ṣayẹwo awọn ti wọn gba fọọmu naa daadaa lasiko ifọrọwanilẹnuwo ti awọn ṣe fun wọn, awọn ọtalelọọọdunrun-un ni wọn si yege.

O ni obinrin mẹtalelọgọrun-un lo wa ninu wọn, nigba ti awọn ọrinlelugba o din mẹta to ku jẹ ọkunrin.

Nipa bi wọn ṣe mu awọn obinrin naa, Aderibigbe ṣalaye pe awọn mu obinrin mẹta-mẹta latijọba ibilẹ kọọkan awọn eeria ọfiisi to wa ni Mọdakẹkẹ.

O ni wọn yoo bẹrẹ ipagọ (camping) lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ninu ọgba ileewe Wọle Ṣoyinka High School, to wa niluu Ejigbo.

Lara awọn nnkan amuyẹ ti awọn ti wọn yege ọhun gbọdọ mu lọwọ lọ si ipagọ naa ni iwe-ẹri “ara mi da ṣaka” lati ileewosan to ba jẹ ti ijọba, bẹẹ ni wọn yoo tun mu aṣọ awọsoke (vest) funfun, ṣokoto penpe alawọ buluu ati ṣibi ijẹun.

O fi kun ọrọ rẹ pe eyikeyii ninu wọn ti ko ba de si ibi ipagọ laarin aago mẹjo aarọ si aago mẹfa irọlẹ ọjọ Sannde, yoo padanu anfaani naa, igbimọ ọhun yoo si fi ẹlomiiran rọpo rẹ.

Leave a Reply