Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Jamiu Shittu, ọmọkunrin ẹni ogun, ọdun ti gbadajọ ẹwọn oṣu mẹfa bayii niluu Abẹokuta. Eyi ri bẹẹ nitori o bo ṣe ja nẹẹti to wa loju windo ibi to ti fẹẹ ji ororo ti wọn n pe ni ẹnjinni ọili ọhun, nibi to ti fẹẹ fa irin oju ferese naa yọ lọwọ ti ba a.
Ọjọ kesan-an, oṣu kẹwaa yii, ni Jamiu huwa ole naa lagbegbe Sawmill, loju ọna OGTV, Ajebọ, niluu Abẹokuta.
Agbefọba Ọlakunle Ṣọnibarẹ to ka ẹsun meji ti i ṣe igbiyanju lati jale ati ile fifọ si Jamiu lẹsẹ ṣalaye pe ọmọ ẹyin ọkọ ni Jamiu jẹ fun olupẹjọ, Ọgbẹni Kazeem Ọbajimi.
O ni lalẹ ọjọ to fẹẹ ji ẹnjinni ọili yii, niṣe lo mọ-ọn-mọ lọọ jokoo sinu mọto ọga rẹ, to ni ilẹ ti ṣu, oun ko le lọ sile mọ. Nigba ti gbogbo eeyan si lọ tan lo gba ibi ti ọga rẹ n ko ẹnjinni ọili naa si lọ, o ja ọkan lara awọn nẹẹti to wa loju ferese ibẹ. Nibi to ti n gbiyanju lati yọ irin oju ferese naa kuro ni ọlọdẹ to n ṣọ ibẹ ka a mọ, ti si mu un.
Jamiu ko le jiyan, Agbefọba Ṣọnibarẹ sọ pe o jẹwọ pe ẹnjinni ọili loun fẹẹ ji ninu ọfiisi to wa, oun fẹẹ gba oju ferese naa wọle ni.
O ni olujẹjọ yii tun jẹwọ pe eyi kọ ni igba akọkọ toun yoo jale, oun naa loun ti n fọle, toun si n ji ọpọlọpọ nnkan to ti sọnu ninu ọfiisi naa tẹlẹ. Nigba ti wọn si beere lọwọ ẹ pe ṣe o jẹbi tabi bẹẹ kọ, Jamiu to n gbe laduugbo Ajibowo, Ifọ, nipinlẹ Ogun, sọ pe oun jẹbi.
Adajọ O.M Ṣomẹfun lo gbọ ẹjọ rẹ, o paṣẹ pe ki ọmọ ogun ọdun yii lọọ ṣẹwọn oṣu mẹfa tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira ( 50,000)