Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ alagbeeka kan niluu Idanre ti ni ki awakọ kan, Samson Akingbasọtẹ, lọọ fẹwọn oṣu mẹrin jura fun riru ofin gbaluu-mọ to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Agbefọba, Ọlayẹmi John, sọ nigba ti igbẹjọ n lọ lọwọ pe ọwọ tẹ ọdaran ọhun to n kiri laarin aago meje aarọ si mẹwaa aarọ ti eto kolẹ-kodọti n lọ lọwọ.
Ẹsun keji to fi kan ọkunrin naa ni pe o tun gbiyanju lati ba ọkan ninu awọn agbofinro to n mojuto eto naa ja nigba ti wọn n beere ohun to n wa kiri lasiko naa lọwọ rẹ.
Niwọn igba ti olujẹjọ ti gba pe oun jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, ile-ẹjọ alagbeeka ọhun ni ko lọọ fẹwọn oṣu mẹrin gbara, tabi ko san ẹgbẹrun marun-un Naira gẹgẹ bii owo itanran.
Bakan naa ni wọn tun pasẹ fun un pe o gbọdọ san ẹgbẹrun meje Naira fun oṣiṣẹ eleto aabo to fiya jẹ lasiko ti wọn fẹẹ fi pampẹ ofin gbe e.