Oṣu mẹta ni Kọlade yoo fi dari ọkọ loju titi n’Ilọrin, oyinbo kan lo lu ni jibiti

Stephen Ajagbe, Ilọrin,

Fẹsun fifi ifẹ ẹtan lu obinrin oyinbo kan ni jibiti lori ẹrọ ayelujara, ile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin ti paṣẹ fun Kọlade Emmanuel Balogun lati dari ọkọ loju titi fun oṣu mẹta, ko si tun san ẹgbẹrun lọna aadọta naira owo itanran. Adajọ Sikiru Oyinloye lo paṣẹ naa nigba tajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ajẹbanu, EFCC, wọ ọ lọ sile-ẹjọ.

Ọwọ tẹ Kọlade to n pe ara rẹ ni Willam Davis, ninu oṣu kẹta, ọdun 2020, pẹlu awọn atẹranṣe ori ikanni gmail: Willamdavis@gmail.com, eyi to fi n lu jibiti.

Olujẹjọ naa loun jẹbi nigba tile-ẹjọ ka ẹsun naa si i leti.

Agbẹjọro ijọba, Aliyu Adebayọ ni niwọngba ti olujẹjọ ti loun jẹbi, pẹlu awọn ẹri to daju to wa niwaju ile-ẹjọ, ki adajọ da ẹjọ rẹ bo ba ṣe tọ.

Ṣugbọn agbẹjọro olujẹjọ, Rotimi Ọyagbọla, rọ adajọ lati foju aanu wo onibaara rẹ, ko si din ijiya rẹ ku, nitori pe igba akọkọ ree to maa ṣe iru nnkan bẹẹ.

Adajọ Oyinloye ni ọdaran naa yoo bẹrẹ didari ọkọ lati ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹjọ, titi de oṣu kẹwaa, ọdun yii.

O ni ijọba ti gbẹsẹ le awọn foonu ati kọmputa alaagbeka ti EFCC gba lọwọ rẹ.

 

Leave a Reply