Ọṣun 2022: Ajọ eleto idibo gbe orukọ awọn ti yoo dupo gomina ati igbakeji wọn jade

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ajọ eleto idibo lorileede yii, INEC, ti gbe orukọ awọn oludije mẹẹẹdogun ti yoo koju ara wọn ninu idibo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii jade.

Gẹgẹ bi adari iroyin fun ajọ naa, Festus Okoye, ṣe fi sita, ninu awọn ẹgbẹ oṣelu mẹẹẹdogun ti yoo kopa, awọn mẹfa pere ni wọn fa obinrin silẹ gẹgẹ bii igbakeji.

Lara awọn ti orukọ wọn jade ninu iwe naa ni Ọnarebu Lasun Yusuf ti ẹgbẹ Labour Party, Sẹnetọ Ademọla Adeleke fun ẹgbẹ PDP, Alhaji Gboyega Oyetọla fun ẹgbẹ APC, Dokita Akin Ogunbiyi fun ẹgbẹ Accord, Dokita Oyelami Saliu fun ẹgbẹ NNPP ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn ẹgbẹ ti wọn fa obinrin kalẹ gẹgẹ bii igbakeji wọn ni ẹgbẹ ADP, BP, NNPP, NRM, YPP ati ZLP.

Okoye waa sọ pe ki ẹgbẹ ti aṣiṣe ba wa ninu orukọ oludibo rẹ tete fi to ajọ naa leti ko too di pe ọrọ yoo bọ sori.

Leave a Reply