Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Pẹlu bi igbaradi ṣe ti bẹrẹ ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ Ọṣun lori idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun yii, awọn ẹgbẹ oṣelu ti kọwe bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa pe alaafia yoo jọba, ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe meje pere lara awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun to wa lorileede yii ni wọn fara han ninu ipade naa, sibẹ, gbogbo wọn ni wọn ṣeleri lati ba awọn ọmọ ẹgbẹ wọn sọrọ lati gba alaafia laaye.
Awọn ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa nibẹ ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, All Progressives Congress, Social Democratic Party, Labour Party, YPP, ADP ati ADC.
Nigba ti Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, n sọrọ nibi eto naa, o ni ni bayii ti eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu kọọkan ti bẹrẹ, o pọn dandan fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu lati ni ọrọ ajọsọpọ.
Ọlọkọde, ẹni ti Igbakeji rẹ, Kanayo Val, ṣoju fun sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu gbọdọ fi to ileeṣẹ ọlọpaa leti, ki wọn si gba aṣẹ ko too di pe wọn a maa kora jọ fun ipade tabi ipolongo ibo.
Idi eyi, gẹgẹ bo ṣe sọ ni lati le pese aabo fun wọn, ki awọn janduku ma baa lo anfaani ikorajọpọ wọn lati fi da wahala silẹ laarin ilu.
O ke si gbogbo wọn lati ba awọn ọmọlẹyin wọn sọrọ lori gbogbo ọna ti alaafia yoo gba jọba nipinlẹ Ọṣun lasiko idibo ọdun yii.
Nigba to n ba ALAROYE sọrọ, Alaga ẹgbẹ oṣelu SDP, Dokita Ṣọla Ọladẹhinde, ṣalaye pe ẹgbẹ alaafia ni ẹgbẹ awọn, oun si mọ daju pe ko si nnkan ti yoo yatọ ninu idibo yii nitori ibawi wa ninu ẹgbẹ naa.