Ọṣun 2022: Ile-ẹjọ ni Ọmọọba Babayẹmi lofin mọ gẹgẹ bii oludije fun ẹgbẹ PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun kan to fikalẹ si ilu Ijẹbu-Jeṣa, ti sọ pe Ọmọọba Dọtun Babayẹmi ni ojulowo oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ti ofin mọ.

A oo ranti pe igun meji ni wọn ṣedibo abẹle lati yan ọmọ oye ẹgbẹ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Sẹnetọ Ademọla Adeleke lo jawe olubori lọdọ awọn ti wọn ṣe tiwọn ni papa iṣere nla ilu Oṣogbo, nigba ti Ọmọọba Dọtun Babayẹmi jawe olubori lọdọ awọn ti wọn ṣe tiwọn ni gbọngan WOCDIF, niluu Oṣogbo.

Lọjọ keji ni awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa niluu Abuja, labẹ alaga wọn, Ayu, fun Ademọla Adeleke ni satifikeeti lati dupo gomina ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.

Ṣugbọn ninu iwe ipẹjọ kan to ni nọmba HIJ/6/2022, eleyii ti Adedokun Ademọla atawọn eeyan mọkandinlọgbọn mi-in pe ta ko ẹgbẹ PDP ati ajọ eleto idibo, INEC, ni wọn ti sọ pe ki ile-ẹjọ fi oju ofin wo ohun to ṣẹlẹ ni abala mejeeji lọjọ idibo naa.

Onidaajọ Adeyinka Aderibigbe, waa sọ ninu idajọ rẹ lẹyin atotonu awọn agbẹjọro pe awọn aṣoju, dẹligeeti, ti wọn dibo yan Babayẹmi lọjọ naa jẹ ojulowo, wọn si ṣe bẹẹ nibamu pẹlu idajọ ile-ẹjọ kan to waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Idajọ yii, gẹgẹ bi Aderibigbe ṣe ṣalaye, lo fidi rẹ mulẹ pe awọn aṣoju okoolelugba o din marun-un kaakiri wọọdu nipinlẹ Ọṣun lẹtọọ lati dibo gẹgẹ bii dẹligeeti ninu idibo ti wọn yoo fi mu ọmọ-oye fun ibo gomina.

Bakan naa ni kootu paṣẹ fun ẹgbẹ PDP ati ajọ INEC lati ma ṣe fọwọ si idibo abẹle miiran yatọ si eyi ti wọn ti yan Babayẹmi.

Bẹẹ ni kootu fagi le gbogbo igbesẹ ti ẹnikẹni ba gbe lodi si idajọ ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, eleyii to fọwọ si awọn alakooso wọọdu ti wọn yan awọn dẹligeeti ti wọn kopa ninu idibo abẹle ẹgbẹ naa.

Leave a Reply