Ọlawale Ajao, Ibadan
Lọjọ Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ to kọja, lakewi agbaye nni, Alhaji Ọlanrewaju Adepọju, pe ẹni ọgọrin ọdun laye. Gbogbo eeyan lo ti foju sọna pe ariya nla ni baba onijinlẹ ede Yoruba yii yoo ṣe nitori iwọnba eeyan l’Ọlọrun fun loore–ọfẹ lati lo ọgọrin ọdun loke eepẹ, ṣugbọn baba naa jọ awọn ololufẹ ẹ loju, o loun ko ni ariya kankan an ṣe ni toun.
Ọgbọnjọ, oṣu kẹfa, ọdun 1940, ni wọn bi Ọlanrewaju ọmọ Adepọju. Baba to n ba tọba–tijoye jokoo, ti ijọba paapaa ki i si i fọrọ ẹ ṣere nigba kan yii lẹni to ya batani ohùn ewi ti gbogbo akewi n lo lonii.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lori ayajọ ọjọọbi ọhun lopin ọsẹ to kọja, baba aloyinlohun yii sọ pe ibẹru Ọlọrun, ailowolọwọ ati ailalaafia ni ko jẹ ki oun pero kankan fun ariya ọjọ pataki ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘Ọgbọnjọ, oṣu kẹfa, layajọ ọjọọbi mi. Mi o pe ẹnikẹni fun ayẹyẹ kankan. Eeyan le fẹẹ ṣe nnkan nigba mi-in ko jẹ ọtọ ni nnkan to wa ninu eto Ọlọrun Ọba fun oluwa ẹ. Owo ati ilera lo ṣe ipenija. Ṣugbọn ka gba f’Ọlọrun, ka si b’Ọlọrun duro leeyan o fi ni i ṣi ẹsẹ gbe.
“Bakan naa, gbogbo ilakaka ọmọ ẹda gbọdọ ba t’Ọlọrun mu. Eeyan le ti ara ariya ṣiṣe ṣẹ Ọlọrun nigba mi-in, bo tiẹ jẹ pe ki i ṣe gbogbo ariya naa lo n mu ni ṣẹ Ọlọrun, gbogbo ẹ wa lọwọ erongba ti eeyan ba fi ṣe e ati ọna to ba gba ṣe e.
Nigba to n sọrọ nipa idi ti awọn eeyan ko ṣe gburoo ẹ mọ nidii ewi kike, Adepọju sọ pe ọtọọtọ loju tawọn eeyan fi maa n wo nnkan. Ṣugbọn ni toun, nitori ibẹru Ọlọrun ati sisa ti oun n sa fun ohun ẹ̀ṣẹ̀ ile aye.
“Ko si beeyan ṣe le yẹra fun iṣẹ ti gbogbo aye ti mọ ọn mọ, ṣugbọn ohun to jẹ mi logun ju ni pe ewi ti mo n ke yii, ka tun da a pada sọdọ Ọlọrun. Igbesẹ yii nitumọ si mi, o si nitumọ si Ọlọrun ọba to da mi.”
O waa dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ fun aduroti wọn nigba idẹrun ati nigba ipọnju.