Ọwọ tẹ awọn to fi sogun-dogoji lu awọn ara Igboho ni jibiti

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin ọdun meji ti wọn ti n lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri ilẹ Yoruba, ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ awọn oníwàyó mẹjọ kan lẹyin ti wọn ti lu ẹgbaagbeje eeyan ni jibiti niluu Igboho, nipinlẹ naa.

Owo to n lọ bii miliọnu mẹjọ Naira lawọn alagbari wọnyi fọgbọn ẹ̀tàn gba lọwọ awọn ara Igboho ki wọn too dero atimọle ọlọpaa nigba ti aṣiri wọn ti tu sawọn araalu naa lọwọ pe wàyó pọnbele lawọn araabi waa siluu awọn lati lu.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nibẹrẹ oṣu keje, ọdun 2020 yii, lawọn jagunlabi gbórí wọlu Igboho pẹlu ikede pe ki awọn eeyan waa maa forukọ silẹ fun eto ẹyawo ti ko ni èlé ninu.

Ọsẹ mẹta pere ni wọn da fawọn araalu naa pe wọn yoo fi ri ọpọlọpọ owo ya lẹyin ti wọn ba ti san owo iforukọsilẹ ati owo ìyáwó. Bi owo ìyáwó ti ẹnikọọkan ba fi silẹ ba ṣe pọ to ni yoo ṣe rowo ya to.

Ṣugbọn nigba ti awọn araalu lọọ ba awọn eeyan yii nigba ti asiko ati maa gbowo to, niṣe ni wọn  tun fi ọsẹ kan mi-in kun asiko ti wọn ni lati waa gbowo. Nigba ti asiko keji yii yoo si fi pe, awọn anikura ti dẹni àwátí n’Igboho.

Eyi lo mu ki awọn araalu lọọ fiṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti nigba ti ọna awọn afurasi ọdaran ọhun ti jìn, ti wọn ko tilẹ si ni gbèrígbèrí ipinlẹ Ọyọ mọ.

Iṣẹ aṣekara odidi ọsẹ meji lo gba awọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjale (SARS) ipinlẹ Ọyọ ki wọn too ri awọn afurasi onijibiti naa mu. Ilu Badagry, nipinlẹ Eko, ni wọn ti ri awọn mẹjẹẹjọ mu.

Meji ninu awọn olubi eeyan yii, iyẹn Damọla Ademuyiwa ati Dada Adisa, ko ju ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25) pere lọ.

Orukọ awọn mẹfa yooku ni Oyejọbi Kọla, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32); Adisa Ọlayinka, ẹni ọdun mẹtalelogoji (43); Ridwan Adebayọ, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn (26); Rọmọkẹ Ọladipupọ, ẹni ọdun mọkandinmlogoji (39); Adegbọla Ẹniọla, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ati Damilọla Adejumọ to jẹ ẹni ọgbọn (30) ọdun.

Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran yii fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, ti ṣeleri lati gbe awọn eeyan naa lọ si kootu laipẹ jọjọ.

O waa rọ awọn araalu lati maa ṣewadii finnifinni nipa ohunkohun ti wọn ba fẹẹ ṣe papọ pẹlu ajeji, paapaa bi nnkan naa ba jẹ mọ owo ati ààbò

One thought on “Ọwọ tẹ awọn to fi sogun-dogoji lu awọn ara Igboho ni jibiti

Leave a Reply