Oṣere-binrin yii sunkun kikoro nitori bi ọkunrin onitiata kan ṣe lu u nilukulu

Monisọla Saka

Ọkan ninu awọn onitiata ilẹ wa lobinrin to ṣẹṣẹ n goke bọ, Temitayọ Morakinyọ, ti pariwo sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii. O fẹsun kan ọkan lara wọn to jẹ aṣaaju fun un lagbo tiata, Shonẹyẹ Ọlamilekan, ti inagijẹ ẹ n jẹ Papa Showw, pe o lu oun nilukulu lasiko ti wọn wa loko ere kan niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Ninu fidio kan tobinrin naa gbe sori Instagraamu rẹ lo ti sọ eleyii di mimọ.

Pẹlu omije loju ni oṣerebinrin naa fi n sọrọ, bẹẹ lo n fọwọ kan awọn ibi ti ọkunrin naa ti ṣe e leṣe ni gbogbo oju, ara ati bi ete ẹ ṣe bẹ, to si n yọ ẹjẹ, nitori pe o lọọ fẹjọ ẹ sun awọn to jẹ ọga fawọn mejeeji l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọhun.

Nigba to n sọ bọrọ naa ṣe jẹ, Temitayọ ni oko ere lawọn wa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, nigba ti Papa Showw pe oun bii ẹni pe ọmọ ọdọ ẹ lo n ba wi pe koun waa lọọ ra nnkan mimu wa foun. O ni ọna to gba ba oun sọrọ laarin ero dun oun, bẹẹ lo si ti oun loju, ṣugbọn oun ko tori bẹẹ fesi tabi kọ iṣẹ to ran oun.

Temitayọ ni nigba toun pada de, toun si dari sinu yara ile itura ti wọn gba foun, oun gba ọdọ awọn ọga fawọn, Niyi Johnson ati Afeez Ọwọ lọ, oun si fẹjọ sun wọn, tawọn mejeeji ọhun si ṣeleri lati ba a sọrọ, ki wọn si yanju ọrọ naa.

“Ohun ti mo ro ni pe ẹni kan ninu awọn mejeeji pe e lọjọ yẹn lati ba a sọrọ lori nnkan ti mo sọ fun wọn, afi bo ṣe deede wa sibi ta a ti n ṣere, ohun pẹlu awọn eeyan kan lati waa lu mi. Niṣe lo bẹrẹ si i da ẹṣẹ bo mi loju, bo ṣe n lu mi lo n rọjo epe le mi lori.

“Awọn eeyan n fa a pada pe ko fi mi silẹ, ṣugbọn ko dahun, titi to fi fi ẹṣẹ bẹ ete mi, tiyẹn si n ṣẹjẹ.

Awọn mọlẹbi mi ti n pe fun idajọ ododo bayii, nitori bi Showw Ọlamilekan ṣe lu mi nitori ọti Orijin to ni ki n ba oun ra. Abi ṣe ọmọ ọdọ ẹ ni mo jẹ ni. Ẹ woju mi, ẹ wo ẹnu mi, ẹ wo bi Papa Showw ṣe na mi, nitori Orijin. O daa o, to ba jẹ pe bayii lẹ ṣe n ṣe lagboole tiata yii, o daa o”.

‘’Ẹ jọọ, kin ni ẹbi mi nitori Ọlọrun? Mo lọ sibi to o ran mi, mo jiṣẹ to o ran mi lai lanu sọ nnkan kan. Bo tilẹ jẹ pe nigba to maa pe mi laarin awọn yooku mi ta a jọ n sọrọ, ‘Iwọ lọọ ra nnkan mimu wa fun mi’, lo sọ, mo kọkọ wo ẹyin wo lati mọ boya emi lo n ba wi, nitori a ki i ṣe ọlọrọ lọ titi bẹẹ. Bo ṣe ba mi sọrọ nigba to fẹẹ ran mi niṣẹ yẹn dun mi, o si ti mi loju. Afi bo se waa ko lulu bo mi, nitori pe mo fẹjọ ẹ sun awọn Bọda Niyi”.

Pẹlu omije loju ni obinrin yii fi n sọrọ, to si n pe fun idajọ ododo ta ko iya ti Papa Showw fi jẹ ẹ, pe iya naa ko gbọdọ jẹ oun gbe

Leave a Reply