Ọlawale Ajao, Ibadan
Latari iwe ẹsun ti ọkunrin agbẹjọro kan, Amofin Niyi Ọkanlawọn, kọ ta ko ijọba ipinlẹ Ọyọ, ileeṣẹ ọlọpaa lorileede yii, ẹkun keji to wa niluu Oṣogbo, ti mu awọn afurasi ọdaran meji lori ẹsun ọhun.
Amofin Ọkanlawọn, to jẹ agbẹjọro Ọgbẹni Dapọ Davies, lo kọwe ẹsun ọhun pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ ilẹ nipinlẹ Ọyọ fontẹ lu ilẹ kan ṣoṣo feeyan meji ọtọọtọ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kọwe ẹsun kan ṣọwọ si Gomima ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pẹlu agọ ọlọpaa to wa ni Iyaganku, lori iṣẹlẹ yii.
Ninu ẹsun naa l’Ọkanlawọn ti fẹsun kan awọn lọgaa-lọgaa nileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ ilẹ pe wọn ṣe makaruuru ilẹ pẹlu bi wọn ṣe ta ilẹ kan fun ẹlomi-in lẹyin ti wọn ti kọkọ ta a fun Ọgbẹni Dapọ Davies lọdun 2013.
Wọn waa rọ Gomina Makinde ati ileeṣẹ ọlọpaa lati tete da si ọrọ naa ko ma baa di wahala ti agbara wọn ko ni i ka.
Akọroyin wa gbọ pe awọn ọlọpaa teṣan Iyaganku ti mu awọn afurasi kan lori iṣẹlẹ yii, ti wọn si kilọ fun wọn pe wọn o gbọdọ ṣiṣẹ kankan lori ilẹ ọhun titi ti awọn yoo fi pari iwadii awọn.
Ṣugbọn wọn ti fun awọn eeyan afurasi arufin naa lanfaani lati gba beeli wọn.
ALAROYE gbọ pe lasiko ti gbogbo aye n reti abajade iwadii awọn ọlọpaa yii lawọn igun keji ti wọn lu ilẹ ọhun lontẹ fun tun lọọ ṣiṣẹ lori ilẹ naa.
Iṣẹlẹ yii lo fa a ti wọn fi kọwe ẹsun mi-in ṣọwọ si igbakeji ọga ọlọpaa ilẹ yii to wa lẹkun keji, niluu Oṣogbo, awọn ni wọn si n ṣewadii iṣẹlẹ ọhun lọwọlọwọ bayii.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn mu awọn afurasi meji lori iṣẹlẹ yii, wọn si kilọ fawọn eeyan naa pe ẹnikẹni ko gbọdọ de ori ilẹ naa mọ titi tawọn yoo fi pari iwadii awọn.