Oṣiṣẹ kootu atawọn agbẹjọro fẹhonu han l’Ọṣun, wọn ni iyanjẹ ijọba ti pọ ju

Florence Babaṣọla

Lati aago mẹsan-an aarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu nipinlẹ Ọṣun (JUSUN) ati ti awọn agbẹjọro (NBA) ti kora wọn jọ siwaju ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo lati fẹhonu han lori ohun ti wọn pe ni aibọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ latọwọ awọn gomina lorileede yii.

Oniruuru akọle lawọn eeyan naa gbe lọwọ, wọn ni awọn fẹẹ da duro, ki awọn wa lominira awọn, kijọba tuwọ lori sisan owo-oṣu atawọn ajẹmọnu mi-in gẹgẹ bo ṣe wa ninu abala okoolelugba o le ẹyọ kan ninu ofin orileede wa.

Alaga awọn JUSUN l’Ọṣun, Ọgbẹni Eludire, sọ pe patapata la a fọju lawọn yoo fi iyanṣẹlodi naa ṣe, titi digba tijọba yoo fi dahun ibeere awọn.

O ṣalaye pe awọn ko bẹ ijọba o, bẹẹ ni awọn ko ni i sinmi, afi kijọba fi owo-oṣu awọn silẹ, kawọn wa lominira nitori pe ko lẹtọọ kijọba maa jẹ gaba le awọn lori.

Lati iwaju ile-ẹjọ giga ni Oke-Fia, ni wọn ti wọ lọ sile-ẹjọ giga tijọba apapọ lagbegbe Abere, ko too di pe wọn kọja si sẹkiteriati ijọba ni Abere.

Leave a Reply