Oṣiṣẹ kootu jale, ni wọn ba wọ wọn lọ sile-ẹjọ l’Oṣogbo

Florence Babasola, Oṣogbo

Igi a fẹyinti, to jẹ gbogbo ara kiki ẹgun lọrọ awọn oṣiṣẹ ile-ẹjọ giga meji nipinlẹ Ọṣun ti ọwọ tẹ laipẹ yii lori ẹsun ole-jija. Awọn olujẹjọ naa, Adedoyin Adebọwale, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ati Sulaiman Tajudeen, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta ni wọn fẹsun kan pe wọn ji beba itẹwe (Typing Sheet).

Inspẹkitọ Adeoye Kayọde to gbe wọn wa si kootu ṣalaye pe ogunjọ, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni wọn huwa naa ninu ọgba ile-ẹjọ giga to wa niluu Oṣogbo.

O ṣalaye pe ṣe lawọn mejeeji gbimọ-pọ, ti wọn si ji odidi beba mẹfa ọhun ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira (#30,000).

Adeoye ni iwa naa lodi, bẹẹ lo si nijiya labẹ ipin ọrinlelọọọdunrun o le mẹta ati okoolelẹẹẹdẹgbẹrun o din mẹrin (516) abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2002 tipinlẹ Ọṣun n lo.

Awọn olujẹjọ mejeeji ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun igbimọ-pọ huwa naa.

Leave a Reply