Ọṣinbajo ko dalẹ ẹnikẹni lori pe o fẹẹ dupo aarẹ Naijiria o-Ọlaoye

Jọkẹ Amọri
Ẹgbẹ kan to n ronu fun Ọjọgbọn Ọṣinbajo lori eto idibo to n bọ yii ti wọn pera wọn ni ‘Ọṣinbajo Think Tank’ ti fi idunnu wọn han si bi Igbakeji Aarẹ naa ṣe jade, to si fifẹ han lati dije dupo aarẹ ilẹ Naijiria lọdun to n bọ. Wọn ni igbesẹ to daa lo gbe, ko si dalẹ ẹnikẹni lori ipinnu to ṣe yii.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Gbenga Ọlaoye, lo sọrọ yii di mimọ nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ Tẹlifiṣan Arise, niluu Eko.
Ọkunrin naa ni oriṣiirisii iriri ti Ọṣinbajo ti ni nile ijọba laarin ọdun meje to fi ṣe igbakeji aarẹ, ati awọn amuyẹ loriṣiiriṣii to ni nipa awọn ẹkọ to kọ ati awọn ileewe to lọ, wa lara ohun amuyẹ lati pese eto ijọba awa-ara-wa to dara fun awọn ọmọ Naijiria ati orileede Naijiria.
Nigba to n dahun ibeere lori boya jijade Ọṣinbajo lati dupo aarẹ jẹ iwa ọdalẹ, ọkunrin naa ni ki i ṣe iwa ọdalẹ rara, bẹẹ ni ki i ṣe iwa afojudi.
O ni ẹgbẹ to n ronu fun Ọṣinbajo lori ọrọ oṣelu yii gbagbọ gidigidi pe bi ọkunrin naa ṣe jade pe oun fẹẹ dupo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023, ko ni nnkan kan an ṣe pẹ̀u iwa ọdalẹ tabi afojudi rara. O ni kaka bẹẹ, niṣe ni ijade rẹ fi aaye silẹ fun awọn eeyan ti wọn nifẹẹ Naijiria lati panu pọ, ki wọn si dibo fun ọkunrin naa lati di aarẹ ilẹ wa lọdun to n bọ lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe.
Ọlaoye ni ki Ọṣinbajo too jade rara lawọn ọmọ orileede yii ti n ri apẹẹrẹ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oun ni yoo gbapo naa lọwọ Aarẹ Buhari to ba kuro nibẹ.
O fi kun un pe, ‘‘ijade ti Ọṣinbajo jade ni lati tẹsiwaju nibi ti Buhari ba a ade, mo si mọ daju pe oun ni ipo naa tọ si, nitori o jẹ ọlọpọlọ pipe, bẹẹ ni yoo ṣe awọn atunṣe to ba yẹ to ba debẹ.’’
Ọkunrin yii ṣapejuwe Igbakeji Aarẹ naa gẹgẹ bii ẹni to gbọn ṣaṣa, to si jẹ olotitọ si gbogbo iṣẹ ati ipo ti wọn yan an si. O fi kun un pe jijade ọkunrin ọmọ bibi ilu Ikẹnnẹ yii fi han pe Naijiria ko ni i pẹẹ lu aluyọ.
O ni pẹlu awọn orisiirisii agbeyẹwo ti oun ti ṣe, o fi han gbangba pe Ọṣinbajo ni aayo ti awọn araalu n fẹ lati bọ sipo aarẹ.

Leave a Reply