Ọṣinbajo ko lasidẹnti o, awọn to nijamba lo ran lọwọ

Ọrẹoluwa Adedeji
Oludamọran pataki lori eto iroyin fun Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Laolu Akande, ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ tawọn kan n gbe kiri pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni ijamba mọto.
Ninu atẹjiṣẹ kan to fi ranṣẹ si ALAROYE lo ti sọ pe ko si ootọ ninu iroyin ẹlẹjẹ ti awon kan n gbe kiri pe Igbakeji Aarẹ ni ijamba mọto. O ni nigba ti Ọṣinbajo n lọ si papakọ ofurufu lati tẹsiwaju ninu irinajo rẹ lọ si ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, lati lọọ ba wọn kẹdun lo ri awọn to ni ijamba naa lo ri awọn to nijamba mọto yii, to si duro lati ran wọn lọwọ.
Niṣe ni mọto wọn takiti, eyi lo mu ko da mọto rẹ duro, ti oun atawọn ẹṣọ to n rinrin-ajo pẹlu rẹ si ṣaajo wọn, to ni ki ọkọ pajawiri to n tọju alaisan to wa lẹyin rẹ gbe awọn to fara pa lọ si ọsibitu fun itọju to peye, ki wọn si fun oun labọ bi oun gbogbo ba ṣe lọ si.
Ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni Ọṣinbajo lọ si ilu Ọwọ, nibi to ti lọọ ba wọn kẹdun lori bi awọn afẹmiṣofo ṣe pa eeyan rẹpẹtẹ ninu ijọ St Francis Catholic Church.

Leave a Reply