Ọṣinbajo ranṣẹ ikini ku oriire si Bọla Tinubu

Jọkẹ Amọri

Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ranṣẹ ikini ku oriire si Aṣiwaju Bọla Tinubu ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo ọdun 2023.
Ninu ọrọ ikini rẹ lo ti sọ pe, ‘‘Mo ki Aṣiwaju Bọla Tinubu fun orire rẹ ninu eto idibo abẹle to ti jawe olubori lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC ninu eto idibo to n bọ.
‘‘Bakan naa ni mo ki Aarẹ Muhammadu Buhari ati gbogbo awọn aṣaaju wa fun aṣeyọri ipade pataki yiyan aṣoju fun ipo aarẹ.
‘‘Fun ọpọlọpọ ọdun, ẹni ti o jẹ oludije ti yoo ṣoju wa yii ti fi ọpọlọpọ ifẹ jijẹ ọmọ orileede to daa ati ọkan akin pẹlu ipinnu han ninu gbigbe orileede wa ga. Ipa to ko ninu ijọba awa-ara-wa ati ilọsiwaju rẹ da a ya sọtọ. Bakan naa ni iriri rẹ yoo jẹ ohun to ṣe pataki ninu igbiyanju ẹgbẹ wa lati ri i pe a ni orileede ti aabo ati ilọsiwaju wa.
‘‘Si gbogbo ẹyin ọmọ ẹgbẹ wa, la fi pe ẹni ti ẹ dibo fun lasiko eto idibo abẹle to kọja yii, gbogbo wa gbọdọ wa ni iṣọkan, ka si gbaruku ti ẹni ti a dibo yan lati gbe asia ẹgbẹ wa lasiko idibo ọdun to n bọ yii lati ri i pe ẹgbẹ wa jawe olubori.
‘‘Gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Onitẹsiwaju tootọ, a gbọdọ duro giri, ki a si wa ni iṣọkan gẹgẹ bii ẹgbẹ lati mu erongba wa lati ṣagbekalẹ orileede ti yoo mu igbe aye to daa, ti o si rọrun fun awọn eeyan wa ṣẹ.’’
Bayii ni Ọṣinnbajo pari lẹta ikini ku oriire rẹ.

Leave a Reply