Oṣu mẹrin ni Samson yoo lo lẹwọn o, adajọ lo ṣẹ sofin eto gbaluu-mọ n’Idanre

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ alagbeeka kan niluu Idanre ti ni ki awakọ kan, Samson Akingbasọtẹ, lọọ fẹwọn oṣu mẹrin jura fun riru ofin gbaluu-mọ to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.

Agbefọba,  Ọlayẹmi John, sọ nigba ti igbẹjọ n lọ lọwọ pe ọwọ tẹ ọdaran ọhun to n kiri laarin aago meje aarọ si mẹwaa aarọ ti eto kolẹ-kodọti n lọ lọwọ.

Ẹsun keji to fi kan ọkunrin naa ni pe o tun gbiyanju lati ba ọkan ninu awọn agbofinro to n mojuto eto naa ja nigba ti wọn n beere ohun to n wa kiri lasiko naa lọwọ rẹ.

Niwọn igba ti olujẹjọ ti gba pe oun jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, ile-ẹjọ alagbeeka ọhun ni ko lọọ fẹwọn oṣu mẹrin gbara, tabi ko san ẹgbẹrun marun-un Naira gẹgẹ bii owo itanran.

Bakan naa ni wọn tun pasẹ fun un pe o gbọdọ san ẹgbẹrun meje Naira fun oṣiṣẹ eleto aabo to fiya jẹ lasiko ti wọn fẹẹ fi pampẹ ofin gbe e.

Leave a Reply