Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, nile-ẹjọ giga kan to wa niluu Ilọrin paṣẹ ki akẹkọọ ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Salau Olumide, gbalẹ titi, ko si tun fọ gọta fun oṣu mẹta gbako, fẹsun jibiti ori ayelujara.
Ajọ to n gbogun tiwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu, EFCC, lo wọ ọdaran naa lọ siwaju Adajọ Sikiru Oyinloye lori ẹsun kan ti wọn fi kan an.
Oyinloye ni ọdaran naa yoo gbalẹ Tankẹ, bẹrẹ lati ikorita to wa nileefowopamọ GTB titi de Abule nla furniture, to wa lọna Fasiti Ilọrin, lati ọjọ keje, oṣu kẹsan-an, titi de ọjọ keje, oṣu kejila, ọdun 2020.
Olumide to n pe ara rẹ ni Rick Freeman lori ẹrọ ayelujara lati maa fi rẹ awọn eeyan jẹ, paapaa awọn oyinbo.
Adajọ tun ni ki ọdaran naa sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira. Bakan naa lo gbọdọ yọju si ọgba ẹwọn to wa ni Mandala, ki wọn gba orukọ atawọn nnkan mi-in nipa rẹ silẹ nibẹ, to ba kọ lati ṣe bẹẹ, ẹwọn oṣu mẹfa lo maa fi gbara.
O ni awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa gbọdọ fiwe sọwọ si akọwe agba nile-ẹjọ giga lọjọ keje, oṣu kejila, ọdun yii, lati fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni ọdaran naa gbalẹ, to si tun ko gọta.
i