Oṣugbo gba oku ọba alaye l’Ayepe, lawọn ọmọ ọba ba gba kootu lọ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ẹjọ kan waye nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun to wa l’Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ohun to ni i ṣe pẹlu ni awọn ọmọ ọba mẹta kan ti wọn pe Oṣugbo lẹjọ, pe wọn gba oku baba awọn ti i ṣe kabiyesi Alaye Aba ti Aba, n’Ijẹbu Ayepe, ọba Rauf Raji-Sulaiman, wọn ko jẹ kawọn sin in nilana to wu awọn.

Obinrin lawọn ọmọọba mẹta to pe ẹjọ yii, orukọ wọn ni Abilekọ Aderonkẹ Egunjimi, Abilekọ Tiwalade Abass ati Abilekọ Adeyẹmi Joseph.

Ohun ti awọn olupẹjọ yii sọ ni pe ẹgbẹ alawo Oṣugbo tẹ ẹtọ awọn loju mọlẹ labẹ ofin, wọn ni bi wọn ṣe gbe oku baba awọn lai jẹ kawọn sin in lodi labẹ ofin ilẹ yii, bẹẹ ni wọn ni ẹgbẹ naa gbọdọ sanwo nla fawọn fun iwa ti wọn hu.

Nigba ti ẹjọ naa n waye niwaju Adajọ Muhammad Shittu, agbẹjọrọ awọn olupẹjọ, Amofin agba Bọlaji Ayọrinde, ṣalaye pe eeyan mẹfa pere loun ṣi fun ni iwe ipẹjọ ninu awọn olujẹjọ mẹrindinlogun tawọn ọmọ ọba yii pe lẹjọ. Ọmọ ẹgbẹ Oṣugbo mẹẹẹdogun lati ilẹ Ijẹbu ati igbimọ iṣẹṣe Ijẹbu kan( Ijebu Traditional Council).

o ni awọn ti adirẹsi wọn wa larọọwọto ni wọn ti gba iwe ipẹjọ naa, bẹẹ lo rọ kootu pe ọna mi-in loun yoo gba mu iwe naa de ọdọ awọn mẹwaa to ku, ki wọn le waa ṣalaye tiwọn pẹlu.

Adajọ Shittu faaye silẹ fun agbejọro awọn olupẹjọ lati pin iwe ipẹjọ naa, bẹẹ ni agbẹjọro awọn Oṣugbo, Amofin Ṣọla Ọpẹodu, naa fara mọ ọn.

 

Lati mọ iha awọn Oṣugbo lori ọrọ yii, ALAROYE ba ọba Ogboni Agba Agbaye, Alagba John Daisi, sọrọ, lori ẹjọ ti awọn ọmọ ọba mẹta yii pe, ohun ti Ọba Ogboni Agba Agbaye sọ ree, ’’ Awọn Oṣugbo lo ni oku baba wọn, nitori nigba ti baba wọn maa jẹ ọba, awọn ọmọ o mọ. Ohun to dẹ jẹ nigba to n jẹ ọba lọwọ, wọn o mọ ọn. Wọn kan ri i pe baba awọn jọba, awọn di ọmọọba-binrin ati ọmọọba-kunrin ni.(Princes and Princesses)

‘’Wọn o mọ ohun to wa nidii ẹ, wọn o tiẹ le wiini keesi yẹn, nitori nigba ti baba wọn wa n’Ipebi fọjọ mọkanlelogun, gbogbo ohun ti wọn ṣe fun baba wọn nibẹ, awọn o mọ ọn.

‘’Awọn ni wọn o ṣetan lati ṣe ohun ti ilu n ṣe, ikọja aaye ni lati gbe Oṣugbo lọ si kootu. Ta lo fẹẹ dajọ naa.

‘’Niṣe lo yẹ ki wọn pada sile, ki wọn bẹbẹ pe kin ni wọn fẹ o. Ohun ti baba wọn jẹ, ki wọn lọọ pọ ọ jade, bi wọn ba ti le pọ ọ, Oṣugbo aa sanwo fun wọn. Ṣugbọn bi wọn ko ba le pọ ọ, dajudaju awọn ni wọn maa sanwo fun Oṣugbo.

‘’Ohun to lewu fun wọn ni wọn n ṣe, wọn ti gbagbe pe lẹyin kootu, wọn aa tun ṣi maa ri awọn Oṣugbo niluu, abi wọn o ni i rira mọ ni. Ṣe iran wọn gan-an ko ni i jọba mọ ni.

‘’Laye atijọ ti ko si ọba, ti ko si ijoye, ti ko si purẹsindẹnti, awọn Oṣugbo lo maa n yanju ọrọ to ba ruju, Ogboni lo maa n yanju ẹ. Fun idi eyi, o yẹ ki wọn pada sile ni’’

Ṣa, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, ni kootu sun igbejọ mi-in si.

Leave a Reply