Ọṣun 2022: Adajọ ni dandan ki INEC mu iwe-ẹri Ademọla Adeleke wa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Onidaajọ Tertsea Kume to jẹ alaga igbimọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ ninu idibo gomina to waye ninu oṣu Keje, nipinlẹ Ọṣun, ti dajọ pe ki ajọ INEC mu iwe-ẹri ti gomina tuntun, Ademọla Adeleke, fi kalẹ fun wọn lọdun 2018, to kọkọ dije wa si kootu.

Ninu idajọ ti ko ju ogun iṣẹju lọ ọhun ni Kume ti sọ pe aṣẹ ti ile-ẹjọ pa pe ki kọmiṣanna ajọ eleto idibo l’Ọṣun mu fọọmu ti Adeleke fi ṣe akọsilẹ awọn iwe-ẹri to ni lọdun 2018 silẹ.

Ṣugbọn ọpọlọpọ ariyanjiyan lo waye lori ẹ nijokoo to kọja, ti awọn igbimọ si sọ pe awọn yoo gbedaajọ kalẹ lori ẹ lonii.

Onidaajọ Kume sọ siwaju pe niwọn igba ti ile-ẹjọ ko ti i gbe ẹsẹ kuro lori aṣẹ to pa pe ki ajọ eleto idibo mu fọọmu naa wa, o di dandan ki wọn bọwọ fun aṣẹ ile-ẹjọ.

Lẹyin naa ni wọn sun igbẹjọ siwaju di Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii.

Tẹ o ba gbagbe, nigbẹẹjọ to kọja ni Kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọṣun, Dokita Mutiu Agboke, sọ fun igbimọ to n gbọ ẹsun to ṣu yọ lẹyin idibo gomina l’Ọṣun pe ko si satifikeeti ti gomina tuntun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lo lasiko to fẹẹ dije lọdun 2018 lakata ajọ naa mọ.

Satifikeeti yii lo ṣatupalẹ awọn iwe-ẹri ti Adeleke sọ pe oun ni ninu Form CF 001 to fi dije dupo gomina lọdun naa lọhun-un.

A oo ranti igbimọ naa ti fun agbẹjọro fun Gomina Gboyega Oyetọla ati ti ẹgbẹ oṣelu APC lanfaani lati fiwe pe kọmiṣanna fun ajọ eleto idibo ọhun lati ko awọn iwe-ẹri Ademọla Adeleke wa si kootu.

Nigba ti igbimọ naa jokoo lọjo Tusidee ọsẹ yii ni agbẹjọro Oyetọla, Oloye Akin Olujinmi (SAN) ran ile-ẹjọ leti nipa iwe ti wọn fi ranṣẹ si REC lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ati pe ohun ti kọmiṣanna naa ba sọ ni yoo jẹ ọpakutẹlẹ ohun ti ẹlẹrii keji ti olupẹjọ fẹẹ pe yoo jẹri le lori.

Agbẹjọro fun olujẹjọ akọkọ to jẹ ajọ INEC, Paul Ananaba, sọ fun ile-ẹjọ pe kọmiṣanna ajọ naa ti ran aṣoju kan wa.

Aṣoju naa, Sheu Mohammed, ẹni to jẹ igbakeji ọga agba lori ọrọ idibo ati iṣakoso ẹgbẹ oṣelu, ṣalaye pe Form CF 001 ti Adeleke fi kalẹ lọdun naa ko si lakata awọn mọ.

O ni ilu Abuja ni wọn mu fọọmu naa lọ, ẹda rẹ (photocopy) nikan ni wọn mu wa si ọfiisi ajọ naa l’Oṣogbo. O ni Form EC8A lawọn ni lọwọ.

Ṣugbọn agbẹjọro fun olujẹjọ sọ fun kootu pe ni kete ti ile-ẹjọ ti beere fun awọn satifikeeti naa lo yẹ ki REC ti ranṣẹ si olu ileeṣẹ naa l’Abuja lati ba a fi ranṣẹ.

Leave a Reply