Ọṣun 2022: Ajibọla Baṣiru ni yoo ṣaaju igbimọ ipolongo ibo fun Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Wọn ti kede agbẹnusọ ileegbimọ aṣofin agba ilẹ wa, Ọnarebu Ajibọla Baṣiru, gẹgẹ bii alaga igbimọ ti yoo ṣe kokaari ipolongo ibo fun saa keji Gomina Adegboyega Oyetọla nipinlẹ Ọṣun.
Ajibọla, ẹni to n ṣoju awọn eeyan Aarin gbungbun Ọṣun l’Abuja, ni awọn alaga lati ẹkun idibo ijọba apapọ mẹsan-an to wa nipinlẹ Ọṣun yoo wa labẹ rẹ.

Nigba to n kede awọn ọmọ igbimọ yii niluu Oṣogbo, alaga ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, ṣalaye pe lara ojuṣe igbimọ naa ni lati ri i pe Gomina Oyetọla ṣaṣeyọri ninu idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.
O ni ki awọn ọmọ igbimọ naa jẹ ojulalakan fi n ṣọri lati tete maa tu aṣiri ẹnikẹni laarin wọn to ba n ṣiṣẹ ta ko erongba agbekalẹ wọn kiakia.
Ninu ọrọ rẹ, Baṣiru sọ pe loootọ lọpọlọpọ le maa ro pe iṣẹ naa le pupọ fun igbimọ naa, ṣugbọn Oyetọla ti mu un rọrun pupọ.
O ni oniruuru iṣẹ idagbasoke ti Oyetọla ti ṣe laarin ọdun mẹta ataabọ lori iṣejọba ti to lati ṣepolongo ibo fun un. O waa ṣeleri pe awọn yoo ṣa ipa awọn lati ṣaṣeyọri iṣẹ naa.

Leave a Reply