Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni iha ẹkun idibo Ẹdẹ, iyẹn Ede Federal Constituency, nipinlẹ Ọṣun, ti sọ pe awọn ko mọ ẹnikẹni to ba gbero tabi jade sita lati ba Gomina Gboyega Oyetọla du ipo naa lọdun to n bọ ri rara.
Wọn kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ jade lati sọ pe oun fẹẹ dupo gomina nitori bii igba pe eeyan fẹẹ fi owo ati asiko rẹ ṣofo lasan ni.
Ninu ipade oniroyin kan ti wọn ṣe ni wọn ti kede pe digbi ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lagbegbe naa wa lẹyin Oyetọla ati pe awọn ko le ṣatilẹyin fun ẹlomiran mọ yatọ si gomina ọhun.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni ẹkun idibo naa, Alhaji Gbadebọ Ajao, ṣalaye pe oniruuru awọn iṣẹ takuntakun ti ijọba Oyetọla ti ṣe lo jẹ ki awọn pinnu lati ṣatilẹyin fun saa rẹ lẹẹkeji, o si da awọn loju pe yoo gbe ipinlẹ Ọṣun debute ayọ.
Ajao fi kun ọrọ rẹ pe awọn aṣeyọri ti ko lẹgbẹ ni Oyetọla ti ṣe lai fi ti gbese gọbọi tijọba ana gbe kalẹ fun un ṣe, pẹlu eto ọrọ-aje to ti dẹnukọlẹ.
O ni bi awọn ṣe n sọ pe Oyetọla lẹẹkan si i naa lawọn n mura lati ri i pe apa ẹkun idibo awọn ni ẹni ti yoo gbapo lọwọ gomina awọn yoo ti wa lọdun 2026.
O ni loootọ lawọn n pariwo ‘Iwọ-Oorun Ọṣun lo kan’ lọdun 2018, ṣugbọn pẹlu iṣejọba alaakoyawọ ati ti iṣẹ idagbasoke ti gomina n ṣe, o ti fun awọn ni itunu lati ṣiṣẹ fun atundi ibo rẹ fun saa keji.
Lara awọn aṣeyọri naa ni sisan owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba lẹkun-unrẹrẹ loorekoore, atunṣe awọn ileewosan alabọọde kaakiri ipinlẹ Ọṣun, eto aabo to duroore, mimu atunṣe ba ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni ti iṣẹ atunṣe awọn oniruuru oju popo kaakiri awọn ijọba ibilẹ to wa ni Ẹdẹ, Ejigbo ati Ẹgbẹdọrẹ, o ni Oyetọla gbiyanju pupọ, idi niyẹn ti awọn si fi n sọ pe ko si ẹnikẹni ti yoo jade ba a dije fun piramari ninu ẹgbẹ APC lati ẹkun idibo naa.