Ọṣun Oṣogbo: Ẹ jokoo sibi ti ẹ ba wa ki ẹ maa wo ayẹyẹ naa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna fun ọrọ aṣa atibudo iṣẹmbaye nipinlẹ Ọṣun, Dokita Ọbawale Adebisi, ti parọwa si gbogbo awọn ti wọn maa n wa sipinlẹ Ọṣun lọdọọdun fun aṣekagba ayẹyẹ ọdun Ọṣun-Oṣogbo lati jọwọ, jokoo sibi ti wọn ba wa, ki wọn si maa wo gbogbo bi eto ba ṣe n lọ lori ẹrọ ayelujara.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ lori imurasilẹ wọn fun aṣekagba ayẹyẹ naa ti yoo waye lọla lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, Ọbawale ṣalaye pe ijọba ko fẹ ki ajakalẹ arun Korona to ṣẹṣẹ de, iyẹn Delta Variant, wọle nipasẹ awọn olubọ Ọṣun.

Nitori idi eyi nijọba ṣe gba ileeṣẹ kan ti yoo maa ṣafihan gbogbo bi eto naa ba ṣe n lọ lori ẹrọ ayelujara, ti awọn eeyan yoo si lanfaani lati wo o nibikibi ti wọn ba wa kaakiri agbaye.

Bakan naa ni Ọbawale tun rọ awọn ti wọn ba wa layiika lati mọ pe ẹmi ko laarọ, ki wọn tẹle gbogbo alakalẹ lati dena itankalẹ arun Koronafairọọsi lasiko aṣekagba ayẹyẹ naa.

O ni ijọba ti ṣeto aabo to nipọn fun ẹmi ati dukia awọn olubọ Ọṣun, oniṣẹmbaye, alejo, awọn oniroyin ati awọn ti ọrọ kan nidii aṣa ati isẹmbaye.

O ni ijọba ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati fara pamọ sabẹ aṣekagba ayẹyẹ Ọṣun Oṣogbo lati da wahala silẹ tabi lati maa dunkooko mọ ẹmi awọn alejo.

Ọbawale ni ki awọn obi ati alagbatọ kilọ fawọn ọmọ wọn lati ma ṣe gba ki ẹnikẹni lo wọn fun iwa-ipa tabi iwa janduku nitori ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ yoo fimu kata ofin.

Bakan naa lo rọ awọn ẹlẹsin-jẹsin nipinlẹ Ọṣun lati ṣiṣẹ papọ ni iṣọkan, ki wọn faaye gba awọn ẹlẹsin yooku lati ṣe ẹsin wọn, ki alaafia si jọba lasiko aṣekagba ọdun naa.

Leave a Reply