O ṣee ṣe ki Buhari ma yọju sawọn aṣofin ti wọn fiwe pe e

 Jide Alabi

Bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n fọkan si i pe Aarẹ Muhammadu Buhari, yoo ba awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin mejeeji sọrọ niluu Abuja l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ṣee ṣe ko ma waye mọ.

ALAROYE gbọ pe bi ọjọ ọhun ti n sun mọ ni oriṣiriiṣii ete ti n lọ nile-igbimọ aṣofin mejeeji nipa bi wọn ṣe fẹẹ dojuti Buhari, pẹlu awọn ibeere gbankọ-gbi, eyi to ti mu awọn gomina ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC rọ ọ pe ko ma ṣe yọju sibẹ rara.

Ṣaaju asiko yii ni iroyin ti gba igboro kan pe Ọjọbọ ni Aarẹ yoo ba awọn aṣofin agba atawọn aṣoju-ṣọfin sọrọ lori eto aabo ti Naijiria wa bayii, paapaa lori bi awọn janduku afẹmi-ṣofo ṣe pa awọn agbẹ onirẹsi ti wọn le ni ogoji danu laipẹ yii.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila yii, lawọn aṣofin ranṣẹ si Buhari pe awọn fẹẹ ri i, ṣugbọn a n gbọ ọ bayii pe, ko daju pe Buhari yoo yọju si wọn.

Bi awọn eeyan kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe ta awọn gomina lolobo, lawọn yẹn naa ti rọ Aarẹ ko rọra jokoo jẹẹ, ti ko ba fẹẹ gba idojuti nla tawọn aṣofin kan ti n mura de e nibi ipade to fẹẹ lọọ ṣe pẹlu wọn.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Monde, ọsẹ yii ni Ọnarebu Kingsley Chinda, aṣoju-ṣofin lati ipinlẹ Rivers to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP gbe aba kan dide lati bẹrẹ bi wọn yoo ṣe yọ Buhari kuro nipo Aarẹ orilẹ-ede Naijria.

Ohun to sọ ni pe ijọba Buhari ti kuna patapata lori eto aabo orilẹ-ede yii, ko si yẹ nipo ọhun mọ gẹgẹ bii adari, niṣe lo yẹ ki awọn tawọn wa nile-igbimọ aṣofin bẹrẹ igbesẹ lati yọ ọ danu.

Nigba ti yoo si fi di ọjọ  Iṣẹgun,Tusidee, ọsẹ yii ni oriṣiriiṣi ipade bẹrẹ, bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n ṣe tiwọn, bẹẹ lawọn PDP naa n ṣe e, lara aabọ ipade ọhun ni wọn si ti gbimọ pọ wi pe ti awọn ko ba rọna lati yọ ọ nipo Aarẹ, ibeere ti yoo ba a loju jẹ lawọn yoo bi i to ba le yọju sawọn.

Yatọ sawọn ti wọn ṣepade bonkẹlẹ yii, awọn eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC naa ṣe tiwọn, ninu eyi ti Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Masari, wa nibẹ.

Leave a Reply