Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ile-ẹjọ Majistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo, ti paṣẹ pe ki awọn akọroyin meji kan, Gidado Shuaib ati Olufẹmi Alfred, lọọ fi ẹwọn oṣu marun-marun jura pẹlu iṣẹ aṣekara tabi ki ẹnikọọkan wọn san owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (100,000). Ẹsun ibanilorukọjẹ ati iwa ọdaran ni wọn fi kan wọn.
Ileeṣẹ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Hillcrest Agro-Allied, to wa ni Kilomita kẹrin, lọna Ajasẹ-Ipo, nipinlẹ Kwara, lo wọ awọn akọroyin mejeeji lọ siwaju ile-ẹjọ pe wọn gbe iroyin kan jade lọdun 2018, ninu iwe iroyin ori ayelujara kan, News Digest, eyi ti wọn pe akori rẹ ni “Inside Kwara Factory where indian hemp is legalized” wọn ni ohun ti iroyin wọn yii n sọ ni pe ileeṣẹ to n dako irẹsi ti di ibi ti awọn oṣiṣẹ wọn ti n fa igbo bo ṣe wu wọn, to si ti ba orukọ ileeṣẹ awọn jẹ jinna.
Iwe ẹsun naa tẹsiwaju pe nitori iroyin buruku ti wọn gbe jade ninu osu Kẹfa, ọdun 2018 yii, o jẹ ki ileesẹ naa padanu eto ẹyawo kan pẹlu aṣepọ orilẹ-ede United Arab Emirate, ti owo naa si to ẹgbẹrun lọna ojilelugba dọla owo ilẹ okeere ($250,000).
Nigba ti Onidaajọ A. S. Muhammad, gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lori ẹsun akọkọ ti i ṣe ibanilorukọjẹ, kawọn afurasi mejeeji lọọ fi ẹwọn oṣu meji-meji, gbara pẹlu iṣẹ aṣekara, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ogoji Naira (40,000), gẹgẹ bii owo itanran.
Lori ẹsun keji, ki wọn lọọ fi ẹwọn oṣu mẹta-mẹta gbara, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira (60,000) gẹgẹ bii owo itanran, ti apapọ owo awọn mejeeji si jẹ ẹgbẹrun lọna igba Naira (200’000).
Adajọ ni anfaani wa fun wọn lati pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun laarin ọgbọn ọjọ pere.