Adewale Adeoye
Bẹẹ ba ri awọn wọda kan ti wọn n lọ kaakiri igberiko nilu Eko, paapaa ju lọ, ti wọn ba n wo ọtun, ti won n wo osi ninu ọja Sabo, niluu Ikorodu, nijọba ibilẹ Ikorodu, nipinlẹ Eko, afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Abubarkar Isiaq, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to jẹ ọmọ Hausa to sa mọ wọn lọwọ ni wọn n wa kiri.
Laaarọ kutukutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni awọn wọda ọhun ko awọn afurasi ọdaran ti wọn n jẹjọ lọwọ wa sile-ẹjọ Majisireeti ‘Candide Johnson Magistrate Court’ to wa lagbegbe Ita-Ẹlẹwa, niluu Ikorodu. Bi wọn ṣe ko wọn wọnu ọgba kootu naa ni wọn ti ko gbogbo wọn pata sinu yara kekere kan tijọba pese silẹ fawọn afurasi ọdaran pe ki wọn maa wa ko too di pe wọn foju wọn bale-ẹjọ.
Lasiko ti awọn wọda ko awọn kan ninu awọn afurasi ọdaran yii lọ sinu kootu ni wọn gbagbe lati ti geeti inu yara tawọn ọdaran ọhun wa. N ni Abubarkar ba lo anfaani naa, niṣe lo tu puru jade ninu yara ọhun, lo ba sa mọ wọn lọwọ.
Loju-ẹsẹ ti afurasi ọdaran ọhun sa tan ni idarudapọ nla ṣẹ̀ẹ ninu ọgba kootu naa, ti aọn wọda si n sa sọtun-sosi, ti wọn n wo yeleyele bii ẹni to bọ lọwọ ọlọpaa kaakiri gbogbo agbegbe kootu naa boya wọn le ri ọdaran ti wọn gbe wa sile-ẹjọ ọhun. Ṣugbọn ọna Abubakar ti jin ni tiẹ. N lawọn wọda naa ba n ti ẹbi ọrọ ọhun sira wọn. Bi wọn ṣe n naka abuku si awọn ọdẹ ẹnu geeti kootu naa pe bawo ni afurasi ọdaran ọhun ṣe raaye sa mọ wọn lọwọ, lawọn ọdẹ to wa lẹnu geeti naa n naka abuku si awọn wọda paapaa pe ki lo de ti wọn ko ti geeti yara ti wọn ko awọn afurasi ọdaran ọhun si wa.
Niṣe ni awọn wọda atawọn agbofinro gbogbo si da girigiri lọ sinu ọja Sabo, nibi ti wọn gbagbọ pe nibẹ ni afurasi ọdaran ọhun maa wa, nitori pe inu ọja naa lo ti huwa ti ko bofin mu to sọ ọ di ọdaran lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Ẹni kan to ba ALAROYE sọrọ ninu ọgba kootu ọhun, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe ṣaaju akoko ti Abubarkar sa lọ lo ti n wo ọtun, to n wo osi bii ole ageti, nigba to si ri i pe ko si ẹnikẹni nitosi lo gbe ere da si i, o sa lọ.
Titi ti akọroyin ALAROYE fi kuro ninu ọgba kootu naa, wọn ko ti i foju kan Abubakar, ọdaran to sa lọ ni kootu.