O ṣẹlẹ! Asẹyin tilu Isẹyin rọ meji ninu awọn ijoye rẹ loye 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Asẹyin tilu Isẹyin, Ọba Abdul Ganiy Adekunle Salawu, ti rọ meji ninu awọn ijoye rẹ, Oloye Raheem Adelọdun, to jẹ Baṣọrun ilẹ Isẹyin ati Oloye Sulaiman Adewale Ọlanrewaju, ti i ṣe Akìísí ilẹ Isẹyin loye fungba diẹ na,  o lawọn ijoye naa n fọwọ pa ida oun loju.

Lati ọjọ kọkandinlọgbọn, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, lọba Isẹyin ti da Baṣọrun ati Akiisi ilu naa duro, ṣugbọn nirọlẹ Ọjọbọ laṣiiri iṣẹlẹ yii too lu sawọn oniroyin lọwọ.

Wọn lo pẹ ti awọn ijoye mejeeji yii ti n foju tẹnbẹlu Asẹyin, ọba naa si ti da wọn duro bẹẹ ri lọdun 2018, ko too da wọn pada lẹyin ti awọn agbaagba ilu kan ba wọn bẹ ọba alade naa.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu ẹda awọn lẹta ọtọọtọ ọhun, ti Ọba Salawu funra rẹ fọwọ si, eyi to tẹ akọroyin wa lọwọ, “Nitori iwa afojudi ati aigbọran rẹ si Asẹyin ilu Isẹyin, Ọba Oba (Ọmọwe)  Abdul-Ganiy Adekunle Salau, pẹlu bo o ṣe n sọrọ ṣakaṣaka si i, to o si n ba awọn ijoye kan ṣepade aboosi lati kọyin wọn si Aṣẹyin, a da ọ lẹbi ìdìtẹ̀-mọ́’ba ati ṣiṣe afojudi sọba.’’

 

Leave a Reply