O ṣẹlẹ, awọn kan ti lọọ ta ilẹ ooṣa n’Ibadan o

Ọlawale Ajao, Ibadan

Iwure ati etutu lawọn ẹlẹsin abilẹ n’Ibadan n fi gbogbo igba ṣe bayii lati pẹtu si awọn alálẹ̀ ilẹ Ibadan ninu pẹlu bi awọn ọmọ abulẹṣowo ṣe ta ilẹ ooṣa to jẹ ti gbogbo ọmọ ilu naa.

Ibi kan laduugbo Àwọ́tàn, lagbegbe Apẹtẹ, n’Ibadan, nibi ti Lágelú, ẹni to tẹ ilu Ibadan do wọlẹ si ni wọn n pe nilẹ ooṣa yii. Lẹyin ipapoda baba nla awọn ọmọ Ibadan yii lawọn agbaagba ilu ya ibẹ sọtọ gẹgẹ bii ilẹ ọ̀wọ̀, eyi ti gbogbo ọmọ Ibadan mọ si Ojúbọ Lágelú, to si jẹ pe lọdọọdun ni wọn maa n lọ sibẹ lati wure fun alaafia ati idagbasoke ilu nla yii.

Ilẹ ọhun ni wọn lawọn ajagungbalẹ̀ n’Ibadan ti ta yii.  Bi wọn ba ta a fẹni to mọ nipa aṣa atiṣe ilẹ Ibadan, ṣe iba san, ọmọ Ibo ni wọn talẹ̀ ooṣa ọhun fun, iyẹn si ti n kọle nla kan sibẹ lọwọ bayii.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, nigba tawọn oniṣẹṣe lọ si ojubọ yii fun eto Ayajọ Iṣẹṣe to maa n waye lọdọọdun l’Ojubọ Lagelu, ṣugbọn si iyalẹnu wọn, ile nla kan ti lalẹ hu nile oriṣa naa.

Eyi lo mu ki awọn agbaagba idile Lagelu rawọ ẹbẹ si Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, ati igbimọ awọn agbaagba ilẹ Ibadan lati wa nnkan ṣe sọrọ awọn to maa n talẹ onilẹ n’Ibadan wọnyi.

Lara awọn to ba awọn oniroyin sọrọ yii gẹgẹ bii adari idile Lagelu ni Mọgaji idile naa, Oloye Lamidi Tiamiyu; agbẹnusọ fun idile Lagelu, Ọgbẹni Lukman Babalọla, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Ita Ẹgẹ ati Oloye Bamidele Ẹlẹrẹ Ogunjẹngbọran Ṣiyanmade to jẹ abọrẹ ojubọ Lagelu.

Oloye Ṣiyanmade ti i ṣe, abọrẹ Ojubọ Lagelu ṣapejuwe iṣẹlẹ yii gẹgẹ bii iwọsi nla ati ẹgbin oniyọrọ fun ilu Ibadan, pẹlu bo ṣe jẹ pe ọga awọn ajagungbalẹ yii, ẹni ti ki i tun un ṣe ọmọ Ibadan, tun lori laya, o tun gba ki ẹni to ta ilẹ yii fun kọrukọ ẹ gadagba gadagba si ara pako pelebe kan lẹgbẹẹ ilẹ naa.

O waa rọ Ọba Adetunji lati kilọ fun olori awọn talẹ̀talẹ̀ Ibadan yii, ẹni ta a forukọ bo laṣiiri, lati ṣọra ẹ gidigidi, bi ko ba fẹẹ fori gbe ẹru ti ko ni i le rori gbe.

Leave a Reply