Olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Fẹmi Gbajabiamila, ti ni ẹwọn n run nimu Minisita fun ọrọ agbegbe Niger Delta, Goodswill Akpabio.
Eyi ko ṣeyin bi ọkunrin naa ṣe sọ pe o purọ mọ awọn aṣofin, ko si ri ẹri fi gbe ọrọ rẹ lẹyin. O ni nidii eyi, awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ran ọkunrin naa lẹwọn.
Lọsẹ to kọja ni awọn aṣofin yii pe awọn lọgaalọgaa ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn Niger Delta yii lati waa ṣalaye awọn owo kan ti wọn ni wọn ṣe baṣubaṣu nileeṣẹ naa.
Nigba ti wọn dewaju igbimọ ọhun ni Akpabio sọ pe ọpọlọpọ awọn iṣẹ akanṣe ti awọn ṣe ti wọn ni kawọn waa ṣalaye yii, awọn aṣofin ni kọntirakitọ to gbaṣẹ ọhun, oun si ṣetan lati darukọ wọn.
Ṣugbọn wọn p’ohun mọ ọn lẹnu lọjọ naa, wọn ko jẹ ko tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ.
Afi bi Gbajabiamila ṣe sọ lẹyin eyi pe irọ buruku ni Akpabio pa mọ awọn aṣofin, lo ba ni oun fun un ni ọjọ meji lati gbe orukọ awọn aṣofin ti wọn gba iṣẹ lọwọ rẹ jade.
Ninu ijokoo wọn to waye ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni olori awọn aṣofin naa ti ni niwọn igba ti oun ko ti ri Akpabio ko mu orukọ wa, ti ko si ni ẹri kankan lati fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, a jẹ pe irọ buruku lo pa mọ awọn.
Nibẹ naa lo ti ni ki wọn pe ọkunrin naa lẹjọ piparọ mọ ni ati ibanilorukọ jẹ.
Bi wọn ba bẹrẹ igbesẹ yii, tọrọ naa si dele-ẹjọ, afaimọ ki gomina ipinlẹ Akwa-Ibom tẹlẹ yii ma rẹwọn he.